Igbimọ to n ṣewadii isẹlẹ Lẹkki ṣabẹwo si mọṣuari awọn ṣọja n’Ikoyi, ni wọn ba lawọn n tun un ṣe lọwọ

Jide Alabi

Niṣe ni oju awọn ṣoja to wa ni ọsibitu wọn to wa ni Ikoyi, nipinlẹ Eko, le koko, nigba ti awọn igbimọ to n ri si ẹsun ifiyajẹni awọn SARS ati wahala to ṣẹlẹ ni Lekki ṣabẹwo sibẹ ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni itẹsiwaju iṣẹ ti wọn gbe le wọn lọwọ.

Awọn ṣọja yii kọkọ ti geeti mọ wọn, ti wọn ko jẹ ki wọn wọle sinu ọgba ọsibitu naa. Wọn ni awọn ko le gba wọn laaye lati wọ ile igbokuu-si ti wọn ni awọn waa ṣabẹwo si nitori awọn n tun un ṣe lọwọ. Lati inu oṣu kẹwaa, ọdun to kọja, ni wọn ni atunṣe naa ti bẹrẹ. Beẹ ni wọn ni awọn igbimọ yii ko sọ fawọn tẹlẹ pe awọn n bọ.

Ọga ṣoja kan, Brigedia Al Taiwo, to ba awọn eeyan naa sọrọ ko kọkọ mu un ni kekere pelu wọn, niṣe loju rẹ le koko, ọrọ naa si fẹẹ di wahala laarin wọn pẹlu bi awọn ọmọ igbimọ naa ṣe n fohun silẹ fun wọn lai bikita ohun to le ṣẹlẹ. Ṣugbọn nigba ti ọkan ninu awọn ọmọ igbimọ naa, Ẹbun Adegoruwa ba ọkunrin yii sọrọ ni wọn yanju ọrọ naa nitubi-inubi.

Lẹyin eyi ni wọn gba wọn laaye lati ṣayẹwo si ile igboku-si awọn ologun naa, ti ọga wọn yii si ṣaaju awọn igbimọ naa lati lọ sibẹ.

Ọkan ninu awọn ọmọ igbimọ yii to tun jẹ ajafẹtọọ ọmọniyan, Ẹbun Olu-Adegboruwa ni awọn gbọ nnkan kan lawọn fi nilo lati ṣabẹwo kiakia si ile igbokuu-pamọ ọhun. O ni ohun ti awọn gbọ yii ni ko jẹ ki awọn sọ fun wọn telẹ ki awọn too lọ sibẹ nitori bi awọn ba sọ ṣaaju lilọ awọn, o le ṣakoba si iwadii ti awọn fẹẹ ṣe nibẹ.

Leave a Reply