Igbimọ to n gbọ ẹsun ifiyajẹni SARS bẹrẹ ijokoo l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Igbimọ tijọba ipinlẹ Ondo gbe kalẹ lati gbọ ẹsun gbogbo awọn ti ọlọpaa ṢARS ti fiya jẹ lọna aitọ ti bẹrẹ ijokoo l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ ta a wa yii.

Alaga igbimọ ọhun, Onidaajọ Adeṣọla Sidiq, ninu ọrọ apilẹkọ rẹ ni awọn iwe ẹsun mejilelọgbọn lo ti tẹ awọn lọwọ lati igba ti wọn ti ṣe ifilọlẹ igbimọ naa ni nnkan bii osu kan sẹyin.

Lẹyin ayẹyẹ ifinimọle ti wọn ṣe l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to n bọ yii lo ni iṣẹ fẹẹ bẹrẹ ni pẹrẹu lori awọn ọkan-o-jọkan ẹsun ti wọn ti fi ṣọwọ si awọn.

Ọjọ mẹta pere, ọjọ Iṣẹgun,Tusidee, Ọjọruu, Wẹsidee, ati Ọjọbọ,Tosidee, lawọn igbimọ ọhun yoo fi maa jokoo laarin ọsẹ titi ti wọn yoo fi yanju gbogbo ẹsun to wa niwaju igbimọ ọhun.

Alaga ọhun rọ gbogbo awọn to ti mu ẹsun wa lati fọwọsowọpọ pẹlu igbimọ yii ki iṣẹ naa lee rọrun fun wọn ni ṣiṣe.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Tori pe wọn yinbọn paayan meji, afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun meje dero ahamọ l’Abẹokuta

Gbenga Amos, Abẹokuta Lati ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un yii, lawọn gende mẹrin …

Leave a Reply

//ashoupsu.com/4/4998019
%d bloggers like this: