Igbimọ to n pẹtu saawọ ninu ẹgbẹ APC ti gunlẹ si Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Aje, Monde, ọṣẹ yii ni ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Kwara gbalejo igbimọ ti apapọ ẹgbẹ naa gbe kalẹ lati pẹtu sọkan awọn ti inu n bi ninu ẹgbẹ oṣelu ọhun nipinlẹ naa.

Sẹnetọ Abdullahi Adamu lo n ṣaaju wọn. Ni kete ti wọn si wọ ipinlẹ naa, ọfiisi Gomina Abdulrahman Abdulrasaq, ni wọn kọkọ gba lọ, ti Adamu to jẹ adari igbimọ ọhun si sọ fun gomina pe awọn to n fapa janu lawọn yoo kọkọ ba sọrọ, lẹyin naa lawọn oloye ẹgbẹ, ko too waa kan awọn agbaagba ẹgbẹ. O ni eyi yoo ri bẹẹ ki awọn ma baa fa ori apa kan da apa keji si, ati pe awọn o ni i faaye gba eyikeyii igbesẹ tabi ọrọ ti yoo pin ẹgbẹ oṣelu naa yẹlẹyẹlẹ tabi ti yoo tabuku iṣejọba ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Kwara.

O tẹsiwaju pe awọn ti wa niluu Ilọrin bayii lati tẹti si ohun to fa ede-aiyede awọn ọmọ ẹgbẹ kan, ohun ti wọn n binu si, awọn yoo si wa ọna abayọ si i, tori pe agbe ma ja kan ko si, aja ma tan ni ko dara.

Gomina Abdulrazak jẹẹjẹ atilẹyin fun awọn igbimọ naa ki wọn le ṣe aseye ti alakan n ṣepo. Lara awọn to dipo oṣelu mu ti wọn gbalejo awọn igbimọ naa pẹlu gomina ni Igbakeji rẹ, Ọgbẹni  Kayode Alabi; Abẹnugan ileegbimọ aṣofin ni Kwara, Họnarebu Salihu Yakubu Danladi; Sẹnetọ to n soju ẹkun idibo ariwa Kwara, Ọgbẹni Umar Sadiq, Sẹnetọ to n soju Guusu Kwara, Ọgbẹni Lọla Ashiru, adele alaga ẹgbẹ oṣelu APC, nipinlẹ Kwara, Abdullahi Samari ati Alaga tuntun ti wọn ṣẹṣẹ digbo yan fun ẹgbẹ naa Ọmọọba Sunday Fagbemi, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Leave a Reply