Faith Adebọla
Ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Igboho, ti sọrọ o, ọkunrin naa ti ṣalaye awọn eeyan to waa ka a mọle ati bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ.
Nigba to n ba ileeṣẹ iweeroyin BBC Pidgin sọrọ lori foonu lo ti ṣalaye pe ni nnkan bii aago aago kan aabọ oru ni oun bẹrẹ si i gbọ iro ibọn ninu ọgba ile oun, ti wọn bẹrẹ si i pariwo pe ‘Sunday Igboho, jade wa, ṣọja ni wa, SS ni wa’ Mo waa yọju loju windo, mo ri wọn ti wọ n wọ aṣọ ṣọja ati ti SS, o ya mi lẹnu gidi nigba ti mo ri wọn pe ki lo le ṣẹlẹ, mi o paayan, mi o si baayan ja, ohun ti mo n ṣe ni lati ja fun awọn eeyan mi, gbogbo awọn iwọde ti mo n ṣe, iwọde alaafia ni. Mo n ja fun awọn eeyan mi nitori awọn Fulani n pa wọn, wọn n fipa ba wọn lo pọ wọn, si n gbowo lọwọ wọn. Mo si ri i pe ijọba ko ṣe ohun to yẹ ko ṣe lori eleyii.
Eeyan meji ni wọn pa ni nnkan bii aago meji oru nigba ti wọn n yinbọn. Gbogbo dukia mi ni wọn bajẹ, wọn ba ọkọ mi jẹ, bẹẹ ni wọn ko miliọnu meji ti mo ko sinu durọọ ninu ile mi.