Ija awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun: Dapọ Abiọdun ni kawọn agbofinro rọ lọ si Ṣagamu

Gbenga Amos, Abẹokuta.
Latari akọlu awọn ẹlẹgbẹ okunkun to waye lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii. Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ti paṣẹ fawọn lọgaa-lọgaa ileeṣẹ agbofinro ati ologun nipinlẹ Ogun, lati gbe ọfiisi wọn lọ sagbagbe Ṣagamu ati Rẹmọ, nipinlẹ naa.
Atẹjade kan ti Akọwe iroyin gomina, Kunle Ṣomọrin, fi lede lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, ọṣu Kẹta yii, sọ pe aṣẹ ti gomina pa ọhun kan Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Kọmanda ọ̀wọ́ karundinlogoji awọn ọmoogun (35 Artillery Brigade) ati ti ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS.
Abiọdun sọ fun wọn pe gbogbo kọlọfin ati ibuba wọn ni ki wọn ṣofintoto rẹ, lati ri i pe wọn fi pampẹ ofin gbe ẹnikẹni tabi ọmọkọmọ to ba wa lẹyin bawọn ẹlẹgbẹ okunkun ṣe fẹmi awọn eeyan ṣofo lọsẹ to kọja yii.
Gomina koro oju si iwa ipaniyan ati idaluru to waye naa, o si parọwa sawọn eeyan agbegbe Ṣagamu ati Abẹokuta lati fọwọ sowọ pọ pẹlu awọn agbofinro ki ojutuu le wa lori ọrọ ẹgbẹkẹgbẹ nipinlẹ Ogun.
O ni kawọn ọdọ to n ṣẹgbẹ buruku naa tete jawọ, tabi ki wọn sa kuro nipinlẹ Ogun ati agbegbe rẹ, tori ọwọ maa too tẹ wọn laipẹ, wọn yoo si fimu danrin lori iṣẹ buruku wọn.
Gomina tun ṣekilọ fawọn obi, o ni:
“Awọn obi ati alagbatọ gbọdọ mọ bawọn ọmọ wọn ṣe maa jawọ ninu iwa ipanle.
“A o fẹẹ gbooorun iwa to le ba alaafia tawọn eeyan ipinlẹ Ogun ti n gbadun latọjọ yii, jẹ, a o ni i faaye gba ẹnikẹni lati ṣe bẹẹ lasiko ijọba to wa lode yii. Gbogbo ohun to ba gba la maa fun un, ẹnikẹni to ba tasẹ agẹrẹ sofin lori ọrọ yii yoo ri pipọn oju ijọba.”
Bẹẹ l’Ọmọọba Abiọdun sọ.

Leave a Reply