Gbenga Amos, Ogun
Ẹni ri nnkan he, to fẹẹ ku nitori rẹ ni ọrọ awọn afurasi ọdaran mẹrin kan ti wọn maa n lu jibiti ori ẹrọ ayelujara, eyi ti wọn n pe ni ‘Yahoo’. Aigbọra-ẹni-ye ni wọn lo ṣẹlẹ laarin awọn gbaju-ẹ yii nigba ti wọn fẹẹ pin miliọnu mẹrindinlọgbọn ti wọn ṣẹṣẹ lu ẹni ẹlẹni kan ni jibiti rẹ, n nija ba de laarin wọn, n lawọn kan ba sopanpa ninu wọn, wọn ji ọkan lara wọn gbe, wọn si lawọn maa pa a danu ni ti ko ba pin eyi to jọju fawọn ninu owo olowo ọhun, amọ ọlọpaa ti ko gbogbo wọn, wọn si ti dero ahamọ awọn ọtẹlẹmuyẹ l’olu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun to wa l’Eleweẹran, l’Abẹokuta.
Orukọ awọn apamọlẹkun-jaye ẹda tọwọ ba ọhun ni, Simeon Agbe, Nicky Messiah, Dọlapọ Ọladapọ ati Yetunde Ṣonọla. Obinrin ni Nicky ati Yetunde.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, ninu atẹjade kan to fi sọwọ s’ALAROYE l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kejila yii, ni lati ijẹjọ, iyẹn Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu yii, lawọn ọmọ Yahoo naa ti ji Haruna Usman gbe, ti wọn si lọọ tọju ẹ pamọ sinu ile kotopo kan labule Orile Imọ, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, ipinlẹ Ogun. Gende naa ti lo ọjọ mẹta lakolo wọn, awọn aladuugbo ti wọn fura si irinsi awọn atilaawi yii, ti wọn si ti gbọ finrin-finrin pe ọmọkunrin kan dawati, ni wọn dọgbọn lọọ ta awọn ọlọpaa lolobo, wọn lo jọ pe abosi ati apamọ-pabo kan ti n ṣẹlẹ laarin awọn ọrẹ to n lọ ti wọn bọ bii ilẹkẹ idi laduugbo naa.
Lọgan tawọn ọlọpaa gbọ eyi ni DPO ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Owode-Ẹgba, CSP Ọlasunkanmi Popoọla, paṣẹ fawọn ọmọọṣẹ ẹ atawọn ọtẹlẹmuyẹ lati lọọ ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ labule ti wọn n sọ ọhun. Ibẹ ni wọn ka awọn ọmọ Yahoo ọhun mọ, wọn ni mẹfa ni wọn, ọwọ ba mẹrin, ọkunrin meji at’obinrin meji, awọn meji yooku ti juba ehoro nigba ti wọn ri ọhun to ṣẹlẹ.
Awọn tọwọ ba yii ni wọn mu wọn lọ sinu ile kotopo ti wọn de Haruna lọwọ lẹsẹ si. Awọn agbofinro lo tu okun ti wọn fi de e, wọn si mu oun naa, niwadii ba bẹrẹ.
Ni teṣan, awọn onijibiti yii jẹwọ pe ni totodo, ọmọ ‘Yahoo’ lawọn, iṣẹ gbaju-ẹ lawọn n ṣe, awọn si ti wa lẹnu ẹ, o pẹ diẹ. Wọn ni laipẹ yii ni pampẹ awọn re, gbaju-ẹ tawọn ṣe fun ẹnikan bọ soju ẹ, miliọnu mẹrindinlọgbọn, ẹgbẹrun lọna irinwo o le mẹtadinlogoji, ati aadọta din lẹgbẹrun kan Naira (N26,437,950) lawọn wọ jade ninu akaunti onitọhun.
Wọn ni Haruna tawọn ji gbe yii lo lewaju iṣẹẹbi naa, ọdọ ẹ ni owo naa n wọle si, nigba tawọn si beere pe ko pin tonikaluku fun un, wọn ni ko dahun, kaka bẹẹ, ẹgbẹrun meji ati igba Naira pere (N2,200) lo fun awọn pe kawọn pin in laarin ara awọn, tori owo naa ko ti i wọle tan, o ni kawọn ni suuru kowo naa tubọ wọle daadaa si i.
Yooba bọ, wọn ni bọwọ kan ba jẹ ti ko fun ekeji jẹ, ọwọ n da ọwọ loro ni, iwa ti wọn ni Haruna hu yii lo mu kawọn fura pe afaimọ ni ọrẹ awọn yii ko ti pinnu lati da nikan jẹ owo to wọle ọhun mọlẹ, bẹẹ awọn jọọ dẹ pampẹ ẹ ni. Eyi lo mu kawọn pinnu lati ji i gbe, lawọn ba tan an lọ sọdọ babalawo kan ni Orile Imọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kejila ọhun, ibẹ lawọn ti rẹn ẹn mọlẹ, tawọn si sọ fun un pe dandan ni ko fun awọn ni ipin to jọju ninu owo tuulu-tuulu ọhun, aijẹ bẹẹ, inu saare ni yoo ti lọọ nawo to ranju mọ naa.
Ṣa, iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii. Awọn ọlọpaa lawọn ṣi n wa babalawo ti wọn de Haruna mọlẹ sakata rẹ nile kotopo, ile awo ẹ, wọn si n wa awọn ọmọ ‘Yahoo’ yooku ti wọn sa lọ. Bakan naa ni iwadii ṣi n lọ lati mọ ẹni to lowo ti wọn fi ọgbọnkọgbọn wọ jade ninu akaunti rẹ yii.
Ni tawọn mẹrin tọwọ ba, ati Haruna to kuro nigbekun ajinigbe bọ si tọlọpaa, gbogbo wọn ti n gbatẹgun lakata awọn ọtẹlẹmuyẹ, wọn si ti n ran wọn lọwọ lẹnu iṣẹ iwadii wọn. Ahamọ ọhun ni wọn yoo ti ṣe ọdun tuntun, ki wọn too taari wọn siwaju adajọ lẹyin tiwadii ba ti pari, gẹgẹ bi Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ṣe paṣẹ.