Ija Ẹrinle/Ọffa: Ọlọfa rọ araalu lati gba alaafia laaye

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ọlọfa tilu Ọffa, Ọba Mufutau Muhammed Gbadamọsi Ajagungbade kin-in-ni, Eṣuwọye keji, ti ke si araalu, paapaa ju lọ, awọn to n da ija silẹ, lati gba alaafia laaye.

Kabiyesi ninu atẹjade kan lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, latọwọ akọwe rẹ, Ọlayinka Kadri, fẹdun ọkan rẹ si ija gbogbo igba to n ṣẹlẹ laarin Ọffa ati Ẹrinle, eyi to fẹmi ati dukia ṣofo.

Ọlọfa ni, “Ilu alaafia niluu Ọffa, emi gan-an si jẹ ẹni to n polongo alaafia laarin ẹya, ẹsin ati ipo yoowu teeyan ba wa. Mo ti fi bi mo ṣe nifẹẹ alaafia han lasiko wahala to n ṣẹlẹ laarin awọn agbẹ ati Fulani darandaran niluu Ọffa ati agbegbe rẹ. Mo koro oju si iṣẹlẹ to ṣẹlẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, mo si ke si awọn adari ilu Ẹrinle lati pana ija naa.”

Kabiyesi gba araalu nimọran lati tẹle aṣẹ konilegbele tijọba pa pe ko gbọdọ si irin laarin aago mẹfa irọlẹ si mẹjọ aarọ, bẹrẹ lati ọjọ kẹrin, oṣu kẹta, ọdun yii.

Leave a Reply