Ija Makinde atiyawo Ajimọbi: Ajimọbi parọ buruku mọ Ariṣekọla ni o

*Aarẹ ko fun un nilẹ kankan

*Ladọja paapaa kọ lo nilẹ

*Ilẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ ni

Alaaji Isiaka Abiọla Ajimọbi ti ku si ọrun bayii, o di ero ọrun, ṣugbọn ko too ku, wahala to wa lori ọrọ ilẹ to kọ ile to ni oun fẹẹ maa gbe si ko tan nilẹ, nigba to si ku tan yii naa, niṣe ni wahala naa n pọ si i. Idi si niyi ti iyawo oloogbe naa, Arabinrin Florence Ajimọbi, ko fi fẹẹ ri Gomina Ṣeyi Makinde, tabi ẹnikẹni ninu ijọba rẹ nipinlẹ Ọyọ soju, ti ọrọ naa si ti di ohun to tan ka ilẹ Yoruba pata, to di ohun ti awọn ara Abuja paapaa n da si. Ajimọbi n kọ ile nla kan si ẹgbẹ ile ijọba, to tun ja si sẹkiteriati l’Agodi, n’Ibadan, ile naa nẹnẹ. Ori pulọọti mejidinlaaadọta (48) lo n kọ ile naa si, o ṣe odo ẹja sibẹ, o ṣe odo iluwẹẹ (Swiming Pool), o ṣe biriiji sibẹ, ati awọn ohun meremere mi-in ti yoo mu oju mẹkunnu pooyi ti wọn ba ba ibẹ kọja. Ko si ẹni kan to kọ ile si ori ilẹ to pọ to bẹẹ nigboro Ibadan, ti Ajimọbi ni iba jẹ akọkọ.

Gbogbo ero ọkunrin naa ni pe ẹgbẹ oṣelu awọn, iyẹn APC, ni yoo wọle, ti ọmọ oun, Adebayọ Adelabu, yoo si di gomina. Bi Adelabu ba di gomina ni, ko si ẹni ti yoo gbọ kinni kan bayii, wọn yoo kan maa royin ile Ajimọbi bii ẹni to n royin ile Adebisi Idi-Ikan ni, awọn oloṣelu ẹgbẹ rẹ yoo si maa waa ba a nibẹ lati ṣe faaji, awọn paapaa yoo si maa royin ile Ajimọbi. Ṣugbọn riro ni teniyan, ṣiṣe ni ti Ọlọrun Ọba. Ajimọbi to fẹẹ di sẹnetọ ko wọle, Adelabu to fẹẹ ṣe gomina naa ko wọle. Ṣugbọn ninu oṣu kin-in-ni si ọṣu keji, ọdun 2019, ko too di pe wọn dibo jake-jado Naijiria, ti Ajimọbi si ti mọ pe oun n lọ, o ṣeto awọn ilẹ kan funra rẹ, o si ṣe fun awọn ti wọn sun mọ ọn. Gbogbo awọn ile to ni ti ko ti i gbawe rẹ tẹlẹ lo sare gbawe fun, pẹlu ero pe bi awọn o ba  tilẹ wọle, ko ni i si wahala fawọn mọ, ohun ti oun ba ti ko lọ bẹẹ, toun ni.

Nigba ti wọn dibo tan ti wọn ko wọle ni nnkan yipada. Abiọla si sare pari awọn iwe ilẹ to ku, ko too di pe o fi ile ijọba silẹ ninu oṣu karun-un, 2019. Ko too kuro nibẹ, wọn ti n kọ ile nla yii sori ilẹ to ni oun ra l’Agodi, o ni ibẹ loun ti fẹẹ lo ifẹyinti oun. Ko sẹni kan to mọ bi ọrọ ilẹ naa ṣe jẹ, koda, ko sẹni to wadii ẹ wo rara. Ṣugbọn ole ni yoo mọ ẹsẹ ole i tọ lori apata, ẹni kan ti wa lẹyin rẹ to n wo iṣe rẹ, Rasheed Ladọja ni. Ṣe ọmọ Ibadan bii ti Ajimọbi loun naa, wọn si ti jọ ṣe gomina ipinlẹ naa ri ni. Ko ti i  pe oṣu keji ti Ajimọbi jade nile ijọba ti Ladọja ti bẹrẹ si i sọ leti awọn ọrẹ rẹ pe oun n lọ si kootu, oun yoo gba ilẹ oun lọwọ Ajimọbi. Njẹ ilẹ wo, o ni ilẹ to wa lori ibi ti Ajimọbi n kọ ile si nni, oun loun ni ilẹ naa, Ajimọbi ji i gbe mọ oun lọwọ ni, asiko si ti to wayi ti oun yoo gba ilẹ naa lọwọ rẹ.

Awọn eeyan ro pe nitori ti ile-ẹjọ ti da Ladọja lare pe ko ji owo kankan ko, ko maa lọ ni alaafia lo ṣe ni oun yoo gba ilẹ oun lọwọ Ajimọbi, ṣugbọn bẹẹ kọ lọrọ ri. Ọjọ kẹsan-an, oṣu keji, ọdun 2019, ni ile-ẹjọ ti da Ladọja lare, ti wọn si gba a kuro lọwọ EFCC to ti n ba a ṣẹjọ lati bii ọdun mọkanla sẹyin pe o ko owo jẹ, bi baba naa yoo ba si gba ilẹ rẹ pada loootọ, asiko naa ni yoo ti lọ sile-ẹjọ, ti yoo si ti pe ijọba ipinlẹ Ọyọ lẹjọ pe ki wọn da ilẹ oun ti wọn gba pada foun. Nitori ẹjọ ti EFCC pe Ladọja pe o fi owo ilu ra dukia ati ile ni ijọba Alao Akala ṣe ni awọn maa gba ilẹ naa kuro lọwọ rẹ ni ọdun 2009. Ohun meji lo jẹ ki wọn gba ilẹ yii. Akọkọ ni pe labẹ ofin, ko yẹ ki ẹni to jẹ olori ijọba ni iru ilẹ bẹẹ, nigba to jẹ oun lo ṣofin pe ki awọn ta awọn ilẹ ijọba to wa lagbegbe Agodi ti ko sẹni to n lo wọn mọ.

Asiko ti Ladọja n ṣejọba laarin 2003 si 2006 lo si ti ra ilẹ yii, labẹ ijọba rẹ naa lo ti ra a. Ẹẹkeji, wọn ko ri akọsilẹ owo ti Ladọja san sapo ijọba gẹgẹ bii owo ilẹ to ni oun ra. Lọna kẹta, ilẹ ijọba ko si fun ẹni to ba ti ni ile tabi ilẹ si agbegbe yii kan naa, ile Ladọja wa ni Bodija, n’Ibadan, o si ni awọn ilẹ mi-in kaakiri ilu naa, ni tododo, ilẹ ijọba kan ko tun tọ si i. Ṣugbọn eleyii ki i ṣe idi ti Akala fi gba ilẹ naa ree o, ija oṣelu aarin wọn nigba naa lo jẹ ki ọkunrin ara Ogbomọṣọ yii fẹẹ fi han ọga rẹ atijọ pe ẹmọ ti kuro ni iye ti wọn n ta a o, ọmọọṣẹ ana ti di alagbara loni-in. Nitori pe gbogbo ọna ni Akala si fi n wa ojuure awọn eeyan nla Ibadan nigba naa, ti ko si si alagbara mi-in to tun ju Aarẹ Ariṣekọla Alao lọ, o pe e silẹ naa, o si fa a le e lọwọ. Gbogbo eleyii ti ṣẹlẹ lati ọdun 2009, bo ba si jẹ Ladọja fẹẹ gba ilẹ rẹ pada loootọ ni, nigba naa ni yoo ti pe ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun.

Ṣugbọn Ladọja ko pe ẹjọ o, koda, ko jọ pe o ranti ọrọ ilẹ naa mọ rara. Idi ni pe ni 2016, lẹyin ti wọn ti dibo ni 2015, ti Ajimọbi wọle, ti oun Ladọja pe e lẹjọ pe oun lo yẹ ki oun ṣe gomina lorukọ Accord, ṣugbọn ti ile-ẹjọ to ga ju lọ da Ajimọbi lare lọjọ kẹta, oṣu keji, ọdun 2016, ti wọn si da oun Ladọja lẹbi. Ladọja pe awọn eeyan rẹ pọ pe ija ti pari, ki gbogbo wọn gbaruku ti Ajimọbi ko le raaye ṣejọba rẹ dadaa. Lati fi ẹmi imoore han, Ladọja beere ilẹ tuntun mi-in lọwọ Ajimọbi. Ilẹ naa wa lẹgbẹẹ ile rẹ ni 26, Ondo Street Bodija, Ibadan. Ọjọ kẹrinla, oṣu keje, ọdun 2016, ni Ladọja kọwe si wọn pe ki wọn fun oun ni ilẹ naa, ilẹ to tobi diẹ ni, nigba to si di ọjọ kọkanla, oṣu karun-un, ọdun 2017, esi de, wọn ni Ajimọbi ti fọwọ si i ki wọn fun un nilẹ to tọrọ. Ni ọjọ kẹrinla, ọṣu karun-un yii, kan naa, Ladọja kọwe lati dupẹ lọwọ Ajimọbi ati ileeṣẹ to fun un nilẹ.

Nigba ti Ladọja n beere ilẹ yii, kinni kan wa to kọ sinu lẹta to fi beere. Ọrọ to sọ naa ni pe ileeṣẹ to n fun wọn nilẹ nipinlẹ Ọyọ ko kuku fun oun nilẹ kankan ri, bi wọn ba fun oun ni eleyii, ko ṣe nnkan kan. Pẹlu lẹta yii, Ladọja gba pe oun ko ni ilẹ kankan nibi kan lọdun 2016. Ṣugbọn loṣu keje, 2019, lẹyin ti Ajimọbi ti lọ, Ladọja bẹrẹ si i halẹ pe oun n lọ sile-ẹjọ, oun yoo gba ilẹ oun pada lọwọ Ajimọbi. Ko jọ pe baba yii nigbagbọ pe ile-ẹjọ yoo gba ilẹ naa foun, ohun to jọ pe o wa lọkan rẹ ni pe pẹlu atilẹyin ti awọn ṣe fun Gomina ipinlẹ Ọyọ tuntun, Ṣeyi Makinde, ko si ohun ti awọn yoo beere ti ko ni i tẹ awọn lọwọ, paapaa bo ba jẹ ti ọrọ Ajimọbi, nitori ko sẹni ti ko gbọ nipa ọpọ iwa ibajẹ ti wọn n pariwo pe ọkunrin naa hu nile ijọba. Nigba ti ijọba Makinde si yẹ ọrọ ilẹ wo loootọ, ni wọn ba fagi le gbogbo ilẹ Ajimọbi, paapaa awọn to gba ni gẹrẹgẹrẹ igba to fẹẹ gbejọba silẹ, ati eyi to fun awọn eeyan kan.

Lara awọn to fun nilẹ ti ijọba ipinlẹ Ọyọ tuntun naa gba pada ni Oloye Bisi Akande ti APC, o fun un ni ilẹ si Agodi, Ọtunba Moses Adeyẹmọ, Ọgbẹni Ọlalekan Alli, Ọgbẹni Adelọdun Ajimọbi. Bi Ajimọbi ti n fun wọn nilẹ yii, bẹẹ naa loun naa n mu awọn mi-in fun ara rẹ, paapaa ni Jericho ati awọn adugbo mi-in  to daa. Ilẹ tirẹ mi-in si wa to jẹ o ku ọsẹ kan ti yoo fi ipo silẹ  gẹgẹ bii gomina lo n fọwọ si wọn. Ọjọ kẹrinla, oṣu keji, 2020 yii, ni Makinde fagi le iwe ilẹ Ajimọbi, to si ni ẹnikẹni ko gbọdọ de ori ilẹ naa mọ. Ṣugbọn ko too di igba naa ni Ajimọbi ti gba ile-ẹjọ lọ, oun ti lọ sile-ẹjọ ni ọjọ kejila, oṣu naa, o ki ile-ẹjọ ba oun gba ilẹ oun lọwọ ijọba ipinlẹ Ọyọ. Ohun to jẹ ko lọ sile-ẹjọ ni pe oun naa ti n gbọ hunrunhunrun pe wọn fẹẹ gba ilẹ ati ile toun ti n kọ sibẹ, nitori awọn ọlopaa ti le oṣiṣẹ danu nibẹ, ti wọn si tilẹkun ibẹ pa lati ọjọ kẹtadinlogun, ọṣu kẹwaa, 2019. Ohun to jẹ ki Ajimọbi pẹjọ niyi.

Ninu ẹjọ ti Ajimọbi pe yii lo ti ni ki wọn ṣe oun jẹẹjẹ o, to si kilọ pe ki ẹnikẹni ma halẹ kan mọ oun, ọrọ ilẹ ti wọn n sọ yii, toun ni, oun loun ni in lati oke delẹ. O ni ki i ṣe pe oun ji i o, bẹẹ ni oun ko si ra a, o ni Ariṣekọla Alao, Aarẹ Musulumi ilẹ Yoruba, lo fun oun nilẹ naa. O fun oun gẹgẹ bii ẹbun ọdun ni. O ni ki i ṣe pe Ariṣekọla deede fun oun ni ilẹ naa lasan kọ, gbogbo iwe ẹ pata lo ko foun, oun si ni wọn lọwọ. Ọrọ yii ni awọn ọmọlẹyin Ajimọbi ati awọn ẹbi rẹ bẹrẹ si i gbe kiri ni gbara ti ọkunrin naa ti ku. Awọn kan tilẹ ti kọ oriṣiiriṣii ọrọ jade, wọn ni awọn wa nibẹ, oju awọn lo ṣe, nigba ti Ajimọbi sọ fun Ariṣekọla pe, ‘Aarẹ, ẹ bun mi nilẹ ti Alao Akala fun yin un-un!’ Awọn yii ni loju ẹsẹ ni Ariṣekọla ti paṣẹ pe ki wọn ko gbogbo iwe ilẹ naa fun un. Ohun tawọn wọnyi n sọ ree, ko si sẹni to le ja wọn, boya irọ ni tabi ootọ, ni o, nitori Ariṣekọla funra rẹ ko si laye mọ.

Awọn ti wọn n gbe iwe yii kiri, iwe ilẹ ti Ariṣekọla fun Ajimọbi yii, wọn ko beere ọna ti Ajimọbi gba to fi ko gbogbo ilẹ to wa ni ẹgbẹ ọtun ati ẹgbẹ osi eyi to jẹ ti Ariṣekọla. Nọmba ilẹ Ariṣekọla ni 361, eleyii si ni Ajimọbi sọ pe wọn fun oun, oun naa lo si wa ninu iwe ẹbun pataki to ni ontẹ ijọba laarin Ariṣekọla ati Ajimọbi. Ṣugbọn ilẹ ti Ajimọbi ṣe fẹnsi yika ki i ṣe Plot 361 nikan. Fẹnsi  to ṣe, ati awọn ibi to kọ ile rẹ si, to si ya batani si wọn jẹ Plot 61, 361 (B) ati 361 (C). Apapọ gbogbo awọn ilẹ to si ko jọ si agbegbe yii jẹ pulọọti mejidinlaaadọta, eyi to tumọ si pe bi eeyan yoo ba kọle onifulaati mẹrin mẹrin ni ile nla, bii aadọta ni yoo kọ sibẹ ti kinni kan ko ni i ṣe. Ajimọbi ko ṣalaye fun awọn ti wọn n gbe itan yii kiri pe arakun ni aṣọ Gbagi o, oun ti ra ilẹ kun ilẹ ti Ariṣekọla fun oun, boya o ra a ko sanwo ni o, boya o si sanwo rẹ, tabi o ni ki ijọba oun foun gẹgẹ bii ẹbun ifẹyinti, ko sẹni to ridii okodoro.

Ijọba Makinde gba ilẹ naa nitori wọn ni gbogbo ibi ti ọkunrin gomina atijọ naa gba yii, ilẹ itan ni. Wọn ni ori ilẹ naa ni ile ti awọn gomina oyinbo laye Western Region n gbe wa, ile naa lawọn gomina aye Awolọwọ, ati ti Akintọla naa gbe, ki i ṣe ibi to yẹ ko bọ si ọwọ ẹni kan. Yatọ si eyi, wọn lo lodi si ofin eto aabo ile ijọba, nitori ọọkan ile ijọba ati sẹkiteeria lo wa, ko si si ohun ti wọn yoo maa ṣe nile ijọba ati ile tuntun ti gomina asiko yii n gbe, ti awọn ti wọn wa nile Ajimọbi tuntun yii ko le maa wo wọn pẹlu kamẹra to ba dara. Wọn ni yatọ si pe ile naa pọ ju fun ẹyọ ẹda eeyan kan ṣoṣo, awọn ohun to rọ mọ ọn pọ ju ki ijọba kan gbe iru ile bẹẹ ta lọ. Idi eyi ni awọn ṣe fa iwe ilẹ naa ya, ti wọn si ni ijọba awọn ko fun ẹnikankan mọ. Ṣugbọn Ajimọbi ni awawi leleyii, Ariṣekọla lo foun nile, ko si sẹni to le gba a lọwọ oun.

Ṣugbọn kọkọrọ kan wa ninu ọrọ yii to ba eyin aja jẹ. Eyi naa si ni pe o jọ pe ***opurọ ni wọn jnn am,o oku orun o, ko ma jẹ awọn alaaye ni wọn n fọhun bii oku orun. Yatọ si pe awọn ọmọ kan ninu ẹbi Ariṣekọla ti dide tẹlẹ pe baba awọn ko fun Ajimọbi nilẹ, iwe ti Ajimọbi n gbe kiri pe Ariṣekọla fi fun oun ni ilẹ yii, ayederu niwe naa, nitori ki i ṣe Arisekọla lo kọ ọ, wọn kan fi orukọ rẹ si i lati fi gba awọn eeyan ati ijọba ipinlẹ Ọyọ loju ni.

Ki ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ ni ipinlẹ Ọyọ too fọwọ si ọrọ ilẹ Ajimọbi yii, lẹta kan ni wọn ni Ariṣekọla kọ si awọn lati adirẹsi rẹ ni Abule Oluwo. Lẹyin oṣu kan ni ileeṣẹ yii si kọwe pada si Ariṣekọla, ti wọn ni awọn ti fọwọ si ohun to beere lọwọ awọn. Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu keji, ọdun 2015 (17/02/15), ni wọn sọ  pe Ariṣekọla kọwe si awọn nipa ọrọ ilẹ ti oun fun Ajimọbi, wọn si da esi pada fun Ariṣekọla yii kan naa ni ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹta, ọdun 2015 (17/03/15). Ṣugbọn Ariṣekọla ti wọn n kọwe si, to n da esi pada fun wọn yii, ti ku lati ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹfa, ọdun 2014 (18/06/14). Eyi ni pe bii oṣu kẹsan-an ti Ariṣekọla ti ku ni wọn sọ pe o kọwe si ileeṣẹ to n ṣeto ilẹ ni ipinlẹ Ọyọ, ti awọn naa si da esi iwe to kọ pada si i.

Afi to ba jẹ oku ọrun n kọ lẹta si araaye lo ku, iyẹn ni Ariṣekọla yoo fi le kọ lẹta si wọn nileeṣẹ to n ṣeto ilẹ ni ipinlẹ Ọyọ laye Ajimọbi, lẹyin ti baba naa ti ku lati bii oṣu mẹsan-an sẹyin. Eyi fihan pe ko le jẹ Ariṣekọla lo fun Ajimọbi ni ilẹ to n wi yii, bo ba si jẹ oun lo fun un nilẹ, ko si iwe kankan lọwọ Ajimọbi, ayederu iwe ni wọn n gbe kiri. Ki i ṣe iwe Ariṣekọla o, irọ buruku ni wọn pa mọ ọn.

One thought on “Ija Makinde atiyawo Ajimọbi: Ajimọbi parọ buruku mọ Ariṣekọla ni o

Leave a Reply