Ija n bọ: Awọn aṣofin ti ni kawọn olori ologun gbogbo fipo silẹ o

Ile-gbimọ aṣofin agba ilẹ yii ti paṣẹ loni-in yii pe ki awọn olori ologun gbogbo fi ipo wọn silẹ kia, ki wọn yẹra nipo naa, ki Aarẹ Muhammadu Buhari le raaye yan awọn olorogun mi-in. Ohun to fa eyi ni bi ọpọlọpọ awọn ṣọja ọmọ Naijiria ṣe n ku soju ogun awọn Boko Haram, ti awọn olori ologun yii ko si ri ọrọ naa yanju lati ọjọ yii wa.

Awọn olori ologun wọnyi ni olori apapọ ọmọ ogun gbogbo, Ọgagun-agba Abayọmi Gabriel Oloniṣakin; olori awọn ṣoja, Ọgagun Tukur Burutai; olori awon ọmọ ogun oju omi, Ọga ologun Ibok-Ete Ekwe Ibas ati olori awon ọmọ ogun ofurufu, Ọga-ologun Sadique Abubakar.

Ni gbara ti Buhari ti gbajọba lo ti yan awọn olori ologun wọnyi si ipo wọn, ṣugbọn wahala awọn Boko Haram to ti wa nilẹ ki wọn too de yii ko kuro nilẹ lati ọjọ ti wọn ti de, kaka bẹẹ, o n le si i ni. Idi eyi ni ọpọlọpọ araalu ṣe ti n sọ pe ki Buhari paarọ awọn eeyan naa, ko mu awon olori ologun tuntun wa, ki wọn le ṣe ayipada eto ijagun awọn ọmọ ogun Naijiria, ki apa wọn le ka awọn Boko Haram to n yọ gbogbo ilu lẹnu. Ṣugbọn gbogbo bi awọn eeyan ti n pariwo to, Buhari ko da wọn lohun, o ni awọn eeyan naa n ṣe iwọn ti wọn le ṣe.

O jọ pe nigba ti ọrọ naa su awọn aṣofin agba yii paapaa ni wọn da si i bayii, ti wọn si ni ki awọn eeyan naa kuro nipo kia. Aṣofin Ali Ndume lo gbe aba naa kalẹ, afi bi awọn aṣofin to ku ṣe gba ọrọ naa ni agbatan, o si han pe gbogbo wọn lo ti n reti iru eleyii tẹlẹ, wọn fẹ ki awọn olori ologun yii fi ipo naa silẹ, gẹgẹ bi ọpọlọpọ awọn araalu ti fẹ.

Ohun ti yoo fa ija ninu ọrọ yii ni pe boya awọn aṣofin yii lẹtọọ lati le awọn olori ologun yii kuro nipo wọn, paapaa nigba ti Aarẹ funra rẹ ko fọwọ si i. Ṣe Buhari lo le le awon olori ologun nipo ni abi awọn aṣofin. Ibẹrẹ ija niyi o.

 

One thought on “Ija n bọ: Awọn aṣofin ti ni kawọn olori ologun gbogbo fipo silẹ o

Leave a Reply