Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ lagbo oṣelu lasiko yii, afaimọ ni ko ni i jẹ ẹgbẹ APC ati Aṣiwaju Bọla Tinubu ni Gomina ipinlẹ Rivers maa ṣiṣẹ fun lasiko eto idibo gbogbogboo to n bọ lọdun 2023, tori gbogbo ọna ni Tinubu n ṣan lati ja ọkunrin naa gba pati mọ ẹgbẹ oṣelu rẹ, PDP, lọwọ.
Ṣadeede lafẹfẹ ọrọ naa fẹ wa yẹẹ, aṣalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹjọ ta a wa yii, wọn ni Tinubu ti n ṣepade pataki kan, ipade atilẹkun-mọri-ṣe ni, pẹlu Gomina Nyesom Wike, niluu eebo.
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn oniroyin lo gbe e pe ilu Paris, lorileede Faranse lawọn mejeeji ti n ṣepade lọjọ Tusidee ọhun, iwadii ti ALAROYE ṣe ti fidi ẹ mulẹ pe niluu London, lorileede United Kingdom ni Wike ati Tinubu ti ṣepade bookẹlẹ wọn, si ni.
Yatọ sawọn meji yii, a gbọ pe Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde ati tipinlẹ Benue, Samuel Ortom wa nipade náà, Wọn ni Gomina ipinlẹ Abia, Dokita Okezie Ikpeazu náà wa pẹlu wọn, bẹẹ si ni Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi ati tipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ko gbẹyin.
Yatọ si pe Wike, Makinde, Ikpeazu ati Ortom jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, ọrẹ lawọn gomina yii, wọn si ṣatilẹyin fun Wike ninu ilakaka rẹ lati di oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu wọn, bo tilẹ jẹ pe ipo naa ko bọ si i lọwọ nigbẹyin.
Bakan naa ni Fayẹmi ati Sanwo-Olu ti wọn jẹ alatilẹyin fun oludije funpo aarẹ ẹgbẹ oṣelu wọn, All Progressives Congress, APC, Bọla Tinubu.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ko gbe atẹjade kankan jade lẹyin ipade naa, awọn ti wọn mọ bi nnkan ṣe lọ lọhun-un sọ pe lajori ọrọ ti ipade naa da lori ni bi Wike yoo ṣe ṣatilẹyin fun Tinubu lasiko idibo to n bọ yii.
Ṣe bi awo ṣe n lu, lawo n jo, ẹnikan to ṣofofo nipa ipade naa sọ pe wọn jiroro lori bi Wike yoo ṣe kọdi sita tọ sile ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, bi yoo ṣe wa ninu ẹgbẹ naa, ṣugbọn ti oun atawọn ẹmẹwa rẹ yoo ṣiṣẹ fun Tinubu.
Bakan naa ni eekan ẹgbẹ oṣelu APC, Ibrahim Masari, ti Tinubu kọkọ yan gẹgẹ bii adele fun ipo igbakeji rẹ tẹlẹ, sọ lọjọ keji ipade London naa pe awọn ti fẹnu ọrọ jona, Wike ti gba lati ṣeranwọ fun Tinubu ko le jawe olubori sipo aarẹ.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe funleeṣẹ oniroyin BBC, Masari ni: “Tori eto idibo sipo aarẹ lọdun 2023 ni ipade naa fi waye, lagbara Ọlọrun, a maa ṣiṣẹ pẹlu Gomina Nyesom Wike. O maa ran wa lọwọ, a si maa jawe olubori pẹlu irọrun, lagbara Ọlọrun.
“ Ṣe ẹ kuku mọ pe Wike ki i ṣe oloṣelu ṣakala, agba-ọjẹ ninu oloṣelu ni, o si tẹwọn daadaa, o tun jẹ gomina, ọwọja eerin ẹ tun de awọn ipinlẹ mi-in yatọ sibi to ti jẹ gomina. Tori eeyan daadaa lawọn araalu mọ ọn si, oun naa si sun mọ wọn daadaa, wọn gba tiẹ. Lagbara Ọlọrun, o wulo fun wa, o si maa ran wa lọwọ.
Masari tẹsiwaju, o ni: “Ṣe ẹ ranti pe APC lo fa iṣubu APC nipinlẹ Bauchi, awọn ọmọ ẹgbẹ wa ni wọn fẹyin gomina ẹgbẹ naa janlẹ funra wọn ninu ẹgbẹ wọn. Ni ipinlẹ Adamawa naa, bo ṣe ri niyẹn. Ohun ti mo fẹ kẹyin eeyan mọ ni pe o ṣee ṣe daadaa keeyan ma darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu kan ṣugbọn ki tọhun ṣiṣẹ fun wọn, to ba fẹẹ ṣe bẹẹ.” gẹgẹ bo ṣe wi.
Tẹ o ba gbagbe, latigba ti ẹgbẹ oṣelu PDP ti ṣeto idibo abẹle wọn nipari oṣu karun-un ọdun yii, lati yan oludije funpo aarẹ, eyi ti Atiku Abubakar jawe olubori rẹ, ti Wike si wa nipo keji tẹle e, ni lọgbọlọgbọ ti bẹ silẹ ninu ẹgbẹ oṣelu naa, paapaa laarin Atiku ati Wike, atawọn alatilẹyin tọtun-un tosi wọn.
Kaka ki ewe agbọn ija naa dẹ, niṣe lo n fojoojumọ le si i, paapaa nigba ti Atiku tun yan Gomina ipinlẹ Delta, Dókítà ifeanyi okowa, gẹgẹ bii igbakeji rẹ ti wọn yoo jọ dije papọ, bo tilẹ jẹ Wike lawọn agbaagba ẹgbẹ kan damọran pe ko mu.
Lẹyin igba naa ni Wike atawọn tiẹ faake kọri pe ohun to le mu kawọn sinmi agbaja, ki alaafia si wa ni bi Alaga ẹgbẹ naa, Sẹnetọ Iyorchia Ayu, ba kọwe fipo silẹ, tori iha Ariwa ti Atiku ti wa loun naa ti wa, ṣugbọn Ayu ti ni ko sohun to jọ ọ, ọdun mẹrin, o kere tan ni wọn dibo yan oun si, ko si sohun to maa le lere fipo silẹ, laijẹ pe saa oun pe.
Eyi kọ ni igba akọkọ ti Tinubu yoo fa Wike loju mọ́ra lati jere atileyin rẹ. Ninu osu kefa to kọja ni wọn ti asiri ìpàdé abenu kan laarin Wike àti Tinubu tí lu síta, wọn lorile-ede Faranse ni wọn ti ṣe é, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwon agbenuso Wike sọ leyin igba naa pe iro ni.
Losu to tẹ́lẹ̀ ẹ, àwọn gómìnà ilé Yoruba nínú egbe APC náà tún sábewo sì Wike ni Ipinle rẹ, Rotimi Akeredolu láti Ondo, babajide Sanwo-Olu láti Eko, Kayọde Fayẹmi lati Ekiti àti Gboyega Oyetọla tipinle Ọṣun wá lara awọn tí wọn lọọ ba Wike sọrọ pe ko máa bọ ni APC.