Ọlawale Ajao, Ibadan
Ẹni a ni ko waa wo gọ̀bì, tó ní kí rèé gọ́bigọ̀bi. Eeyan bomi lámù, o loun ri eégun, ki waa ni ki ẹni to pọnmi sibẹ o ri. Owe wọnyi lo lọ pẹlu agbofinro kan, ẹni ti wọn pe lati waa pẹtu saawọ nibi ti gende meji ti n wọya ija, ṣugbọn ti ọkunrin ti wọn porukọ rẹ ni Saidi yii, dihamọra lọ sibẹ pẹlu bájínátù, to si ṣe bẹẹ yinbọn paayan kan, to tun ṣe awọn meji kan leṣe.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejilelogun (22), oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, niṣẹlẹ ọhun waye ninu ọgba fasiti ipinlẹ Ọyọ, iyẹn Ladoke Akintola University of Technology (LAUTECH), nigba ti ọkunrin agbofinro kan yinbọn paayan nibi to ti n laja, ti ọrọ tiẹ paapaa si ti waa ju ti fọ̀kọ̀làjà nigboro Ibadan, nitori mẹta ọ̀kọ̀ kò yara paayan bii ibọn igbalode.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, awọn akẹkọọ meji ni wọn n wọya ija ninu ọgba fasiti naa, ti okiki ija ọhún si milè titi to bẹẹ, ti akitiyan awọn ẹgbẹ wọn to n gbiyanju lati ka wọn lọwọ ko ko fi seeso rere titi to fi di ohun ti awọn agbofinro n gbọ.
Ṣugbọn ohun to ba ọrọ jẹ ni bi ọkan ninu awọn agbofinro ọhun ṣe deede yinbọn nibi to ti n laja. Loju-ẹsẹ leeyan kan si ti jade laye, ti eeyan meji si tun fara pa.
Iṣẹlẹ yii ni wọn lo bi awọn akẹkọọ ninu ti wọn fi bẹrẹ si i ṣe iwọọde kaakiri lati jẹ ki awọn alaṣẹ fasiti naa mọ pe iku ẹlẹgbẹ wọn naa ko dun mọ wọn ninu rara.
Rogbodiyan yii lo mu ki wọn ti gbogbo ona abawọle sinu ọgba fasiti naa.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, DSP Adewale Ọṣifẹṣọ, ṣalaye fun ALAROYE pe alaafia ti jọba ninU ọgba fasiti naa pada, ati pe awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.