Ija Nnamdi Azikiwe pẹlu ajọ FEDECO to nṣeto ibo lọdun 1979 (2)

Ohun ti ọrọ owo-ori awọn ti wọn fẹẹ du ipo aarẹ lasiko idibo ọdun 1979 yẹn da silẹ, nnkan rẹpẹtẹ ma ni o. Diẹ lo ku ki ọrọ naa da ọpọlọpọ eto ti wọn ti ṣe silẹ fun idibo ọhun ru pata. Nnamdi Azikiwe, baba to fẹẹ du ipo naa lorukọ ẹgbẹ NPP (Nigerian People’s Party), ni ọrọ naa kan ju, nitori oun lo gbe ọrọ naa lori ju lọ. Oun ni ajọ to n ṣeto idibo sọ pe ko sanwo ori, ṣugbọn ti oun ni oun san owo-ori toun daadaa. O ni irọ ni alaga FEDECO, iyẹn Oloye Micahel Ani, pa mọ oun, pe o jọ pe ọkunrin naa ti ni ẹni kan lọkan to fẹ ko du ipo aarẹ, ko si wọle ni. N lọrọ naa ba dija, Ani ni ki eeyan ma sọ iru ọrọ bẹẹ yẹn soun mọ, paapaa nigba to ba tiẹ jẹ gbangba lo ti n sọ ọ, ti awọn oniroyin lorigun mẹrẹẹrin agbaye si pe jọ. Ṣe ohun ti Azikiwe si ṣe niyẹn loootọ, o ko awọn oniroyin aye jọ nibi to ti n ya Ani ati FEDECO balẹ bii agbado ni.

Aminu Kano

Nibi to ti n sọrọ yii paapaa, Azikiwe tahun si Ọbafẹmi Awolọwọ to fẹẹ du ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ UPN (Unity Party of Nigeria), o ni nigba ti Ani ati FEDECO ẹ n pariwo, ki wọn sọ iye ti Awolọwọ san gẹgẹ bii owo-ori ẹ, ki gbogbo aye ba awọn gbọ ọ. Ọrọ yii ka awọn ẹgbẹ UPN lara, wọn ni ewo ni Azikiwe fi onija silẹ to gba alapẹpẹ mu si, ko ma mẹnu ba oludije ẹgbẹ tawọn o, nitori awọn ko ṣetan lati da si ija laarin Azikiwe ati FEDECO, awọn ni wọn jọ mọ ohun ti wọn gba lọwọ ara wọn, ohun yoowu ti wọn ba si jọ da pọ, awọn naa ni ki wọn jọ yanju ẹ. Ṣugbọn UPN ko duro bẹẹ, nitori olootu eto iwadii ati ipolongo wọn, Ebenezer Babatopẹ jade, o si ko iwe owo-ori gbogbo ti Awolọwọ san laarin ọdun mẹta sita. O ni ki gbogbo aye wo iye ti Awolọwọ san ati risiiti to gba, ki wọn le mọ pe ẹni ti ipo aṣaaju tọ si ni UPN fa kalẹ.

Ninu iwe yii lo ti han pe ni ọdun 1976 si 1977, iye ere ti Awolọwọ jẹ lori gbogbo iṣẹ to ṣe jẹ ẹgbẹrun lọna mọkandin ni igba naira (N199,811), owo-ori to si san lọdun naa pẹlu risiiti ẹ jẹ ẹgbẹrun mẹrinlelogoji naira ataabọ (N44,505). Ni ti ọdun 1977 si 1978, Awolọwọ jere lẹnu awọn iṣẹ to ṣe, ere to si jẹ jẹ ẹgbẹrun lọna mẹtadinlọgọsan-an naira (N177,884). Ninu ere to san yii lo ti san owo-ori ẹgbẹrun mejilelọgọrun-un (N102,327), owo naa si bọ si apo ijọba. Ni 1978 si 1979, Awolọwọ ṣe owo, o si jere, apapọ ere to jẹ si jẹ ẹgbẹrun lọna ọrinlelọọọdunrun din mẹrin (376,326), owo-ori to si san lori eleyii jẹ ẹrindinlọgbọn-le-nigba (N226,730) naira. Ni gbogbo igba ti Awolọwọ n san awọn owo-ori yii, eto oṣelu ko ti i bẹrẹ, wọn ko si ti i sọ pe wọn yoo beere owo-ori lọwọ awọn to ba fẹẹ du ipo kankan. Oun kan ṣe tirẹ ni.

Ohun ti wọn n beere lọwọ Azikiwe naa ree, nibi si ni ọrọ ti dija. Azikiwe ni oun san owo-ori ni 1976 si 1977, FEDECO ni ko san owo-ori kankan, pe risiiti to mu wa, lasiko ti eto idibo ti bẹrẹ, lasiko naa lo ṣẹṣẹ lọọ sare san awọn owo-ori to jẹ lati bii ọdun mẹta sẹyin, ohun ti FEDECO si n tori ẹ binu ree, ti wọn ni Azikiwe lu ofin idibo. Ọkunrin oloṣelu NPP naa ko mọ pe awọn ọmọlẹyin Awolọwọ yoo sare ko gbogbo owo ti baba naa ti fi ọdun mẹta san jade bẹẹ lai ṣẹṣẹ maa rojọ, eleyii si mu itiju ba a, nitori ọrọ naa di ariwo pe ti Awolọwọ ba fi le san owo-ori rẹ bayii, ki lo le mu Azikiwe to jẹ aarẹ Naijiria nigba kan ma san owo-ori tirẹ, abi oun naa ko jere nidii iṣẹ to n ṣe ni. Ki i ṣe Azikiwe ni iwe owo ti Awolọwọ sare ko jade yii bi ninu, awọn oloṣelu ẹgbẹ wọn mi-in naa tun fara ya, agaga ẹgbẹ PRP.

Uche Chukwumerije

Bi wọn ti kọwe si Azikiwe ni wọn kọwe si Aminu Kano pe oun naa ko san owo-ori ẹ, ṣugbọn kia ni Aminu Kano ti jade pe oun ko ṣiṣẹ kan ti oun fi le ri owo-ori san. Ṣugbọn nigba ti ọrọ di ariwo, ti awọn eeyan bẹrẹ si i sọ pe kin ni ẹni ti ko ni iṣẹ kan to n ṣe n wa nipo aarẹ, ati pe ẹni ti ko fi ọwọ ara rẹ pawo, ko ṣe iṣẹ aje, bawo ni yoo ṣe mọ ọna lati fi nawo araalu. Nigba ti ọrọ n lọ bayii, ti ẹnu ti bẹrẹ si i kun Aminu Kano ati ẹgbẹ PRP (People’s Redemption Party) rẹ pe alainikan-an-ṣe ni wọn, awọn eeyan naa yi ọrọ pada, wọn ni ki i ṣe bẹẹ, Aminu Kano san awọn owo-ori kan, FEDECO ni ko ṣalaye daadaa iru owo-ori ti wọn n fẹ. Sam Ikoku to fẹẹ du ipo igbakeji aarẹ ẹgbẹ yii ni olori FEDECO, Michael Ani, ni ko ṣalaye to, nitori bẹẹ, niṣe lo yẹ ki ọkunrin naa kọwe fi ipo rẹ silẹ, ko risain, ko lọọ wa iṣẹ mi-in ṣe.

Ẹnu ọrọ yii ni wọn wa ti Awolọwọ fi kọwe owo-ori ti oun san jade. Ni inu ba bi wọn. Inu bi ẹgbẹ PRP. Ni akọwe ipolongo ẹgbẹ wọn ba jade o, iyẹn ọkunrin kan ti wọn n pe ni Uche Chukwumerije, o ni awọn ti ri gbogbo owo-ori ti Awolọwọ san, awọn si ti ri risiiti ẹ, awọn ti wo o pe loootọ lo sanwo, ṣugbọn ko ṣe alaye iṣẹ ti o n ṣe to fi ri iru owo to to bẹẹ, bo ba jẹ iṣẹ lọọya yii naa lo n ṣe, afi ko to orukọ awọn onibaara rẹ ti wọn n gbe ẹjọ fun un jade, igba yẹn leeyan too le mọ ibi ti owo nla bayii ti wa. Chukwumerije ni ohun to han ninu owo rẹpẹtẹ ti Awolọwọ n pa wọle lọdọọdun yii ni pe o ṣee ṣe ko jẹ baba naa n ṣiṣẹ fun awọn eeyan tabi ijọba orilẹ-ede kan ni, awọn ni wọn si n ko owo to to bayii kalẹ, nitori bi ilu ṣe le to yii, o ṣoro ki ẹni kan to maa pa iru owo ti Awolọwọ n pa.

Nigba ti awọn PRP naa ti jade lati bẹrẹ si i ta ko FEDECO ati ọga wọn yii, o jọ pe Azikiwe ti gba agbara kun agbara ni, nigba to si di ọjọ keje, oṣu karun-un, ni 1979, baba naa gba ile-ẹjọ lọ ni Anambra. O ni ki ile-ẹjọ ba oun yẹ ọrọ oun wo, ki wọn si fọwọ si i pe oun san owo-ori, ki wọn si paṣẹ fun FEDECO ki wọn ma yọ orukọ oun danu, tabi ki wọn ma ba oun lorukọ jẹ pe oun ko san owo to yẹ ki oun san. Ajọ to n ṣeto idibo, ati olotuu eto idajọ ilẹ wa ni Azikiwe pe lẹjọ yii, ile-ẹjọ giga niluu Enugu to wa ni ipinlẹ Anambra nigba naa lo si wọ wọn lọ. O ni ni ibi tọrọ de duro bayii, oun ko ni agbojule kan bayii ju ile-ẹjọ lọ, pe oun mọ pe ile-ẹjọ nikan lo ku to le gba oun lati ba oun tun orukọ oun ti awọn FEDECO fẹẹ ba jẹ ṣe, awọn naa ni wọn si le paṣẹ fun FEDECO ko ma ja oun kulẹ lori idibo to n bọ, ko ma fiya jẹ awọn ọmọ Naijiria ati awọn to fẹran oun.

O ni oun sanwo ori, oun si ti ṣetan lati ko risiiti gbogbo siwaju adajọ, nitori oun ko mọ idi ti FEDECO fi da oun ya sọtọ, ti wọn n fẹẹ doju ti oun ni gbangba. Nigba ti wọn pe ẹjọ naa, kia lọkunrin kan ti fo dide, Jaja Wachukwu lorukọ ẹ, oun ni minisita ọrọ ilẹ okeere lasiko ijọba alagbada ti wọn ṣe ni 1959 si 1965. Ọkunrin naa loun ni agbejọro Azikiwe, oun ti ko gbogbo iwe-ẹri tile-ẹjọ nilo wa, nitori bẹẹ, oun ko fẹ ki ẹjọ naa falẹ rara, bi wọn ba fẹẹ bẹrẹ ẹjọ ohun bayii bayii, oun ti ṣetan, nitori awọn ko fẹ ki ẹjọ naa da iṣeto idibo duro rara, oun fẹ ki ile-ẹjọ tete yanju ohun gbogbo. S. A. Ọjọmọ naa dide, o ni FEDECO loun tori ẹ wa, bẹẹ si ni S. C. Unigwe ni lati ọdọ olootu eto idajọ ilẹ wa loun ti wa, lori ọrọ Azikiwe yii naa si ni. N lariyanjiyan ba bẹrẹ niwaju adajọ, Adajọ Emmanuel Araka, adajọ agba ipinlẹ Anambra.

Obafemi Awolowo

Bi Wachukwu ṣe n fẹ ki wọn tete gbọ ẹjọ naa kiakia nitori o mọ pe bi ẹjọ naa ba wọ inu oṣu kẹfa, wọn le yọ Azikiwe danu ninu awọn ti yoo dije du ipo aarẹ, bẹẹ lawọn agbẹjọrọ FEDECO ati tijọba n sọ pe awọn ko le sare ṣiṣẹ naa bẹẹ, afi ki awọn ni to oṣu kan gbako lati fi ṣe e. Wachukwu pariwo, o ni ki adajọ ma gba iru ẹ laaye, nitori o jọ pe awọn kan ti dide lati gbegi dina fun onibaara toun ni. Abi ewo ni ka fi ẹjọ si odidi oṣu kan ninu eto ti ko pe oṣu mọ. Ọjọmọ ni ọrẹ oun kan n laagun ni o, nitori bo ti ri oun yii, lati Eko loun ti n wa, ẹronpileeni loun si n wọ, bẹẹ ni ki oun too le ko awọn iwe ẹjọ yii jọ, ọpọ ibi loun gbọdọ de laarin Naijiria, ko si si bi ko ṣe ni i gba oun loṣu kan. Adajọ Araka wa ni ọrọ to wa nilẹ yii ko gba suẹsuẹ, oun ko fẹ ohun ti yoo di ondupo aarẹ kankan lọwọ, lo ba fi ẹjọ si ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu, o loun yoo bẹrẹ ẹjọ oun.

Lawọn lọọya mẹtẹẹta ba pariwo ni kootu, ladajọ ba dide, lẹyin naa ni awọn lọọya yii ba ara wọn tẹ, ti wọn si sọrọ lori bi ẹjọ naa ko ṣe ni i ni ẹnikankan wọn lara. Ṣugbọn ko too di ọjọ kẹẹẹdogun yii, ọtọ ni ẹjọ ti olupẹjọ agba ni Naijiria, O. A. Ṣoẹtan, gbe jade si ati lọọya atawọn adajọ. Ṣoẹtan ti pe ẹjọ mi-in, ẹjọ to si pe ni pe ile-ẹjọ ti wọn gbe ẹjọ yii wa ko lẹtọọ lati gbọ ẹjọ kankan to jẹ ti ọrọ idibo, nitori ofin ologun to gbe FEDECO dide ko faaye ẹjọ pipe kan silẹ, nitori bẹẹ, o ni ki Adajọ Araka da ara rẹ lẹjọ pe ile-ẹjọ oun ko lagbara ataṣẹ lati gbọ ẹjọ ti wọn gbe wa siwaju oun rara. Bi ẹjọ kan ba wa to lagbara bayii, oun ni wọn yoo kọkọ gbọ ki wọn too le gbọ ojulowo ẹjọ to wa nile-ẹjọ naa gan-an. Nidii eyi, ẹjọ yii ni wọn kọkọ ṣalaye, nibi ti Adajọ Araka ti ni oun fẹẹ gbọ ọrọ lẹnu olupẹjọ agba.

Lọọya FEDECO naa ni bi awọn ba fẹẹ sọ ọ ni asọtun sọ, ko si idi ti Azikiwe fi gbọdọ pe iru ẹjọ yii rara, nitori ko si ẹni kan to ti i da a lẹbi lori ọrọ owo-ori, alaye lasan ni wọn beere lọwọ ẹ, ohun ti wọn n beere ni pe ṣe o sanwo ori tabi ko san an. Ṣoẹtan ni iwe ati risiiti ti Azikiwe ko silẹ ko fihan bii ẹni to san owo-ori nigba to yẹ, pe ki lo waa kan kootu ninu iyẹn. O ni ko yẹ ko pe FEDECO lẹjọ, bẹẹ ni ko yẹ ko pe olootu eto idajọ fun ijọba apapọ lẹjọ. Ṣoẹtan ni bi Azikiwe ba ni iṣoro kan nidii ọrọ owo-ori ẹ, ọdọ ileeṣẹ to n ṣeto owo-ori ni yoo lọ lati ṣalaye ara ẹ, ti yoo ni oun ko ni risiiti to dara lọwọ, ki wọn fun oun ni risiiti to dara. Ko sohun meji ti FEDECO beere lọwọ Azikiwe ju risiiti igba to sanwo lọ, iyẹn to ba ṣe pe risiiti mi-in wa to yatọ si eyi to ti ko kalẹ fun FEDECO yii.

Ṣoẹtan ni yatọ si eyi, ijọba ologun ti paṣẹ ninu ofin idibo ti wọn gbe kalẹ pe ẹnikẹni, tabi ile-ẹjọ yoowu ko gbọdọ da si ẹjọ FEDECO tabi awọn oṣiṣẹ rẹ, bi kinni kan ba wa to ba jẹ ọrọ ariyanjiyan, ijọba apapọ to gbe FEDECO kalẹ ni wọn yoo lọọ ba lati ṣalaye ọrọ naa fun wọn, nitori bẹẹ, ọrọ to wa nilẹ yii ki i ṣe ohun ti Adajọ Araka tabi ile-ẹjọ rẹ le da si rara, ijọba ologun ko fi aaye ẹ silẹ, oun ko si ni i fẹ ko da si ọrọ to le da nnkan mi-in silẹ fun un. O ni odu ni Azikiwe, ki i ṣe aimọ fun oloko, baba orilẹ-ede yii ni, bi ọrọ ba si ru u loju bayii, eyi to fi sare wa si ile-ẹjọ ti ko le da si ọrọ rẹ yii, ọdọ awọn ti wọn ṣofin lo yẹ ko gba lọ. Ṣoẹtan ni bi Azikiwe ba de ọdọ awọn olori ijọba ologun, wọn yoo fun un ni ẹkunrẹrẹ alaye lori ọrọ ẹ, wọn si le jọ yanju ọrọ naa laarin ara wọn. O ni ki Araka dajọ ẹ pe ọrọ to wa nilẹ yii ju ti ile-ẹjọ oun lọ.

Ebenezer Babatope

Nibi ti ẹjọ naa le de, fun odidi ọjọ naa ṣulẹ, wọn ko le gbọ ẹjọ mi-in mọ, ẹjọ kan ṣoṣo ti wọn n gbọ niyẹn, nitori ọrọ naa gbe jẹbẹtẹ le Adajọ Araka lọwọ. Nigba ti Ṣoẹtan ti rojọ tan, ti wọn fa ọrọ naa lọ ti wọn fa a bọ, Araka sun igbẹjọ si ọjọ keji ni, iyẹn ọjọ kẹrindinlogun, oṣu karun-un, ọdun 1979. O ni oun ko le da ẹjọ naa lọjọ naa, oun yoo lọọ yẹ iwe ofin wo, oun yoo si tun fikun-lukun pẹlu awọn ẹlẹgbẹ oun ati awọn ti wọn ju oun lọ. Bẹẹ ni awọn ile-ẹjọ tuka lọjọ naa, ko si sẹni to le da ọrọ Azikiwe ati ti FEDECO silẹ, nitori Ṣoẹtan ti gbe ohun ti Adajọ Araka funra ẹ yoo maa sin le e lọwọ, njẹ yoo le gbọ ẹjọ Azikiwe yii tabi ko ni i le gbọ ọ. Azikiwe ati awọn lọọya rẹ ko fi oju rere wo Ojọmọ ati FEDECO, wọn ni awọn ti mọ tẹlẹ pe abatẹnijẹ ni wọn, ṣugbọn wọn o le ri ti Azikiwe bajẹ, ohun to ba gba lawọn yoo jọ fun un.

Lọjọ keji ti Araka wi naa lo dajọ. Bi ọmọ ba ja ọgbọn kiku lẹẹrun ni o, baba rẹ naa yoo jagbọn lati sin in si ipado. Nigba ti Adajo Araka de lọjọ keji, o ni ọrọ to wa nilẹ yii ki i ṣe ọrọ FEDECO tabi ọrọ idibo, ọrọ owo-ori ni. O ni titi di asiko tawọn yoo fi sọrọ ẹjọ naa tan, wọn ko ti i le dibo tabi ki wọn bẹrẹ eto naa, Nitori bẹẹ, ẹjọ ti oun fẹẹ gbọ yii ki i ṣe ẹjọ ibo didi, ko si ohun to kan oun ninu iyẹn, oun ko si le tapa sofin to jẹ tijọba ologun lati gbọ ẹjọ idibo. Ṣugbọn ẹjọ ti oun fẹẹ gbọ yii, ẹjọ ti ọkunrin kan to n jẹ  Azikiwe ni, nitori awọn kan sọ pe wọn ko ni i ṣeto aabo to yẹ fun un ni, ẹjọ to jẹ pe wọn kan fẹẹ rẹ ẹ jẹ ni, ti wọn si purọ mọ ọn pe ko ṣe ohun to ti ṣe.

Araka ni nitori awọn FEDECO ni Azikiwe ko san owo-ori ni wọn ko ṣe ṣeto aabo to yẹ ki wọn ṣe fẹni to ba fẹẹ du ipo aarẹ fun un, wọn si n fi ẹmi ẹ wewu niyẹn. O ni ohun ti ofin sọ ni pe gbogbo ẹni to ba fẹẹ du ipo aarẹ yii, FEDECO ni yoo pese eto aabo fun un, nitori awọn ni wọn yoo kọwe si ọlọpaa ati ijọba pe ki wọn fun ẹni naa ni ọlọpaa inu ti wọn yoo maa ṣọ ọ. Ṣugbọn FEDECO ko kọwe naa, wọn si n fi ẹmi Azikiwe wewu, o ni ẹjọ to wa niwaju oun niyẹn. Adajọ agba yii ni ipurọmọni ati irẹjẹ yatọ pupọ si eto idibo, ẹjọ ti oun si fẹẹ gbọ naa niyẹn, bi ogo ba si n jẹ ti Ọlọrun, oun funra oun loun yoo gbọ ẹjọ naa. N lariwo ba ta ni kootu, okun buruku ti Ṣoẹtan dẹ silẹ fun aparo, agilinti lo mu ni. Koto ti ọkunrin lọọya ijọba naa ti gbẹ silẹ fun ajanaku, erin moju, erin ko ba ibẹ lọ ni o.

Gbogbo ẹjọ ati atotonu ti Ṣoẹtan gbe kalẹ, gbogbo ọna to gba lati fi gba ẹjọ naa kuro lọwọ adajọ nla yii, gbogbo ẹ ni adajọ naa fi ọgbọn agba yipada, o si ti Ṣoẹtan ati wahala rẹ  ṣubu. Araka ni boun ko ba faaye gba Azikiwe lati sọ tẹnu ẹ, ki ile-ẹjọ si yẹ ọrọ rẹ wo, bo ba si jẹ loootọ ni wọn rẹ ẹ jẹ, a jẹ pe irẹjẹ naa yoo wa titi aye niyẹn, bẹẹ iru nnkan bẹẹ ko dara. O ni oun ko mọ ohun ti ile-ẹjo wa fun ti ko ba le ran mẹkunnu lọwọ, oun ko si ti i ri ofin kan laye yii ti yoo sọ pe ki ile-ẹjọ ma gbeja ẹni ti awọn eeyan tabi ijọba ba fiya jẹ. O ni idi toun yoo ṣe gbọ ẹjọ Azikiwe ree, agbara ile-ẹjọ oun si gbe e daadaa. Nitori bẹẹ, o ni ki gbogbo wọn tun pade ni ọjọ kejilelogun, oṣu karun-un, ọdun 1979 naa, o ni lọjọ naa ni ẹjọ yoo bẹrẹ pẹrẹwu. N ni ohun gbogbo ba tun pa kanrin kese, inu awọn ọmọ Ibo ko dun, bẹẹ lawọn aṣaaju NPP dorikodo, nigba to jẹ pe ko sẹni kan to mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ si Owelle Onitsha, baba ti wọn n pe ni Nnamdi Azikiwe.

Leave a Reply