Ija ọrẹ ẹ ti wọn na lo fẹẹ lọọ gbe tawọn ọmọlẹyin eegun fi gun Ọlatunji pa l’Ekoo

Monisọla Saka

Ija ọrẹ ẹ ni Ismaila Ọlatunji, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn(29), lọọ gbe to fi kuro nile nigba to gbọ pe awọn eegun n ba ọrẹ oun ja lọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ta a wa yii, lai mọ pe irinajo alọọde loun n lọ yẹn.
Ismaila to jẹ iṣẹ telọ lo yan laayo n gbe lagbegbe Isikalu, Olodi Apapa, Ajegunlẹ, nipinlẹ Eko.

Ẹgbọn oloogbe, Ọgbẹni Akanbi Tajudeen Ibrahim, lo lọọ ṣalaye iṣẹlẹ buburu ọhun fawọn ọlọpaa, o sọ bi wọn ṣe gbẹmi aburo oun.
O ni, “Laago mẹjọ alẹ kọja iṣẹju mẹwaa lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, ọrẹ aburo mi to ṣalaisi yii ni wọn sọ pe awọn ọmọ ẹyin eegun lu. Loootọ lawọn ẹni yii maa n wa pẹlu ẹgba ti wọn fi maa n ṣẹruba awọn eniyan.
“Ni Ismaila to doloogbe yii ba mu ọrẹ ẹ yẹn tọ olori awọn eegun naa lọ lati lọọ fẹjọ wọn sun. Bo ṣe n ṣalaye bawọn eleegun ọhun ṣe fiya jẹ ọrẹ ẹ ni ọkan ninu awọn ọmọ ẹyin eegun yẹn ba ja lu ọrọ to n sọ, o ni ki lo de ti Ismaila ṣe n ba ọga awọn sọrọ lọna ti ko mu apọnle wa bẹẹ.

“Lọrọ yẹn ba di ariyanjiyan, titi ti awọn ọmọ ẹyin egungun to ku fi da sọrọ naa. Bi ọkan ninu wọn ṣe mu ọbẹ nla kan ti wọn n pe ni ‘dagger’ to fi gun Ismaila laya niyẹn.
“Lasiko yẹn, emi wa ninu mọṣalaṣi ti mo n kirun lọwọ. Lẹyin ti mo kirun tan ti mo gbọ si ọrọ naa la sare gbe e digbadigba lọ sile iwosan aladaani kan, nibẹ ni wọn si ti dari wa lọ si Oriki. Amọ, o ṣe ni laaanu pe o ti dakẹ ka too gbe e de ileewosan Oriki naa.

“Nigba ti wọn gbe oku ẹ dele, gbogbo adugbo kan gbinringbinrin ni, gbogbo eniyan si n ṣedaro rẹ nitori eeyan jẹẹjẹ to maa n lọ nilọ ẹ ni.
“Lọgan tawọn ti wọn ṣeku pa a gbọ ohun to ṣẹlẹ ni wọn ti na papa bora. Mo si ti fọrọ naa to wọn leti lagọọ ọlọpaa to wa ni Tolu”.
Awọn kan ti ọrọ iku Ismaila ka lara ni wọn ni wọn ti fi ibinu jo mọto alaga awọn eleegun nina nigba ti wọn n fẹhonu han lori iku ẹni wọn.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//lephaush.net/4/4998019
%d bloggers like this: