Jide Alabi
O da bii pe ija agba ti wọn lo n lọ laarin gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Raufu Arẹgbẹṣọla, ati Gomina Isiaka Oyetọla, eyi to ti ran awọn ọmọlẹyin wọn ti rodo lọọ mumi bayii pẹlu bi minisita naa ṣe ki gomina Ọṣun bayii ku oriire ọdun meji to ti lo nipo.
Ninu lẹta kan ti Ministia fun ọrọ abẹle ọhun, Raufu Arẹgbẹṣọla, kọ si ẹni to gbe ipo silẹ fun yii lo ti ni ‘’Mo ki ọ ku oriire ayẹyẹ ọdun keji to o de ipo gẹgẹ bii gomina l’Ọṣun. Iwuri ati inu didun lo jẹ fun mi nigba ti mo boju-wẹyin lori bi o ṣe ja ija nla lasiko idibo, ati bi o ṣe n tẹsiwaju lati mu ijọba onitẹsiwaju maa gbooro si i nipinlẹ Ọṣun.
‘‘Oriṣiiriṣii ipenija lo ti koju, ti aisowo, ajakalẹ arun Korona atawọn mi-in, ṣugbọn o wẹ odo wahala naa ja, o ko si jẹ ki ọkọ ipinlẹ Ọṣun danu.
Mo gbagbọ pe awọn ipenija yii yoo jẹ atẹgun lati bẹrẹ ohun ọtun bi o ṣe bẹrẹ ọdun kẹta saa rẹ yii. Oriṣiiriṣii ipenija lagbo oṣelu, ireti awọn araalu pe ki o tun ṣe si i ju bi o ṣe n ṣe lọ ati bẹẹ bẹẹ lọ, ṣugbọn mo mọ pe o maa bori gbogbo rẹ.
‘‘Jọwọ, tẹsiwaju lati mu itọju awọn ara ipinlẹ Ọṣun ni pataki, awọn ni idi ti ipinlẹ Ọṣun fi wa. Lai si wọn, ko ni si ohun ti a n pe ni oṣelu tabi ipo oṣelu kankan lati wa.
‘‘Lẹẹkan si i, mo ki ọ ku oriire, mo gbadura aṣẹyọri fun ọ lẹnu iṣẹ ati ni gbogbo idawọle rẹ.
Ba mi ki iyawo rẹ, Alaaja Kafayat Oyetọla, ati gbogbo ọmọ igbimọ rẹ nipinlẹ Ọṣun’’
Bi Arẹgbẹ ṣe kọ lẹta naa ree, to si buwọ lu u funra rẹ, to fi ranṣẹ si Gomina Oyetọla.
Eyi ni awọn eeyan gbọ, ti awọn to si ri i naa fi n sọ pe ija ti tan laarin awọn oloṣelu mejeeji yii. Paapaa ju lọ bi Arẹgbẹsọla ṣe fagi le eto kan to ni oun fẹẹ ṣe nipinlẹ Ọṣun lọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii tẹlẹ, eyi to fẹẹ da awuyewuye silẹ laarin awọn alatilẹyin wọn.