Ija Yoruba ati Hausa bẹ silẹ n’Iyana Ejigbo tori alaga kẹkẹ Maruwa ti wọn gun lọbẹ pa

Faith Adebọla, Eko

Ija to gbona lo n lọwọ bayii laarin awọn ọdọ Yoruba ati Hausa to wa lagbegbe Iyana Ejigbo, nipinlẹ Eko, latari bawọn ọdọ Yoruba naa ṣe pinnu lati gbẹsan iku Ọgbẹni Oke to jẹ alaga ẹgbẹ awọn onikẹkẹ Maruwa (TOOAN) agbegbe naa, ti wọn ni Hausa ọlọkada kan gun lọbẹ pa.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mọkanla alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ni ọlọkada ọmọ Hausa kan ti wọn porukọ ẹ ni Audu gba ọna kan ti ko yẹ ko gba lalẹ ọjọ naa, eyi ti wọn lo fa a ti oloogbe yii fi jade si i, to pinnu lati fẹjọ rẹ sun ẹgbẹ ọlọkada.

Ajọ akoroyinjọ ilẹ wa, NAN, ni awọn gbọ ọ latẹnu ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju rẹ pe ọrọ yii ni wọn n fa mọ ara wọn lọwọ ti ija fi bẹrẹ laarin ọlọkada naa ati Ọgbẹni Oke, wọn ni ki wọn too ṣẹju pẹu, ọlọkada naa ti fa ọbẹ aṣooro kan yọ labẹ ijokoo maṣinni rẹ, lo ba gun alaga awọn onikẹkẹ naa lọbẹ, o si sa lọ.

Awọn eeyan diẹ to wa nitosi jade nigba ti wọn gbọ igbe oro oloogbe naa, wọn sare gbe e lọ sileewosan aladaani kan nitosi, ṣugbọn ọkunrin naa dagbere faye lafẹmọjumọ aarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, yii.

Iṣẹlẹ yii ni wọn lo mu kawọn ọmọ ẹgbẹ onikẹkẹ Maruwa pinnu lati foro yaro pẹlu awọn ọlọkada to jẹ Hausa, wọn si bẹrẹ si i ṣe akọlu si eyikeyii ti wọn ba ri ninu wọn, to fi jẹ pe yanpọnyanrin naa mu kawọn eeyan bẹrẹ si i sa kijokijo, ti onikaluku si n sa asala fun ẹmi wọn.

A gbọ pe niṣe lawọn olugbe agbegbe ọhun atawọn to ni ṣọọbu nibẹ tilẹkun mọri pinpin, iṣẹlẹ naa si ti ṣe idiwọ fun kara-kata ọrọ aje, lilọ bibọ ọkọ ati awọn eeyan to n fẹsẹ rin pẹlu.

DPO ọlọpaa tẹsan Ejigbo, CSP Akinṣọla Ogunwale, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni loootọ lọkunrin to jẹ alaga awọn onikẹkẹ naa ti ku, tori ẹjẹ to jade lara rẹ ti pọ ju. O ni oun ti da awọn ọlọpaa jade sagbegbe naa lati dẹkun iforoyaro ati ija ẹlẹyamẹya tawọn ọdọ kan gun le.

Nigba ti ALAROYE pe Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Olumuyiwa Adejọbi, lori aago lati beere ọrọ naa lọwọ rẹ, o ni oun ṣi n reti ẹkunrẹrẹ alaye ni, oun ko ti i le sọ ohunkohun nipa rẹ bayii.

Leave a Reply