Stephen Ajagbe, Ilọrin
Ọjọ Abamẹta, Satidee, ọsẹ to kọja, ni Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq, ṣabẹwo ibanikẹdun si mọlẹbi awọn to padanu ẹmi awọn eeyan wọn ninu ijamba to ṣẹlẹ lori afara Oko-Erin, niluu Ilọrin.
Lara awọn to kọwọọrin pẹlu rẹ ni Alaga igbimọ amuṣẹya to n mojuto ọrọ ayika, (Environmental Task Force), Abdulrazaq Jiddah, atawọn mi-in.
Iyawo ọkan lara wọn, Oloogbe Okechukwu Nwagboo, Abilekọ Ann Okechukwu, dupẹ lọwọ gomina fun abẹwo naa. O ni bii ala ni iṣẹlẹ naa ṣi n jẹ si oun, nitori pe oun ko lero pe ọkọ oun ko ni i mu gbogbo erongba rẹ ṣẹ ko too jade laye.
Ẹni ọdun mejilelogoji lo pe ọkọ rẹ to ku yii, ọmọ marun-un lo si fi saye lọ.
O waa rọ ijọba lati ṣeranlọwọ foun atawọn ẹbi ọmọọṣẹ ọkọ oun mejeeji to padanu ẹmi wọn ninu ijamba naa.
Gomina gbadura pe Ọlọrun yoo tu wọn ninu, yoo si wa pẹlu ẹbi ti wọn fi silẹ.