Ijamba gaasi paayan mẹta n’Ishaga, ọpọ ile ati mọto lo jona

Faith Adebọla

O kere tan, eeyan mẹta lo ku, tawọn bii ọgbọn mi-in si fara pa nibi ijamba gaasi abugbamu kan to waye l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, lagbegbe Iṣaga, nijọba ibilẹ Ifakọ-Ijaye, nipinlẹ Eko. Yatọ sawọn to fara pa, ọpọ ile ati mọto lo fara gba ninu iṣẹlẹ ojiji ọhun.

Nnkan bii aago meji ọsan ọjọ naa lawọn olugbe agbegbe ọhun ṣadeede gbọ iro bii agba ti afẹfẹ gaasi idana kun inu rẹ ṣe bu gbamu, to si gbina. Motọ kan ni wọn loo fẹẹ ja awọn gaasi ọhun si ṣọọbu kan ti iṣẹlẹ naa fi waye.

Ọgbẹni Tunde to ba akọroyin wa sọrọ lori iṣẹlẹ yii sọ pe: ‘Ikẹja ni mo n bọ tiṣẹlẹ naa fi ṣẹlẹ, inu mọto ni mo wa ti mo fi gburoo ibugbamu ọhun, niṣe ni ọpọ eeyan sare fọwọ di eti tori iro naa lagbara gan-an, mi o ti i gbọ iru nnkan bẹẹ ri laye mi.

‘Bi mo ṣe wẹyin bayii, niṣe lawọn eeyan bẹrẹ si da girigiri, ti wọn n sa kijokijo, bẹẹ leefin nla kan gba oju ọrun kan, ọpọ wa la fi mọto silẹ loju titi, tonikaluku sa asala fun ẹmi ẹ, tori sun-kẹrẹ fa-kẹrẹ ọkọ wa nigba yẹn.

‘Bo ṣe di pe ina nla ṣẹ yọ niyẹn, ti a tun n gburoo awọn gaasi mi-in ti wọn n bu gbamu leralera. Ibi ti mo sa si naa ni mo wa ti wọn fi n gbe awọn eeyan kan digbadigba kọja, awọn kan ti ku ninu wọn’.

Ọga ajọ to n ri sọrọ pajawiri lorileede wa (NEMA), ẹka ti Guusu/Iwọ-Oorun, Ibrahim Farinloye, sọ pe bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn oṣiṣẹ alaabo ni wọn ti n ṣiṣẹ lati derọ ina buruku naa, eeyan to ju ọgbọn lọ lawọn ti gbe digbadigba lọ sawọn ileewosan to wa nitosi latari bi wọn ṣe fara gbọgbẹ ninu ijamba ọhun. O ni mẹẹẹdogun lara wọn wa nileewosan Iju Water Works.

Ibrahim fidi ẹ mulẹ pe ọpọ ile ati mọto lo ti jona gburugburu, o ni apa ti n ka ina naa.

Titi di asiko ta a fi n ko iroyin yii jọ, awọn oṣiṣẹ ajọ ọhun ati ti LASEMA, ti ileeṣe panapana, awọn ọlọpaa atawọn oṣiṣẹ Sifu Difẹnsi ṣi n ba iṣẹ lọ lati doola ẹmi awọn araalu, ati lati pana naa.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Nitori ti wọn dari alaisan lọ si ọsibitu aladaani, ijọba da dokita ati nọọsi duro nipinlẹ Ọyọ

Ọlawale Ajao, Ibadan Nitori ti wọn dari awọn alaisan lọ sileewosan aladaani, ijọba ipinlẹ Ọyọ …

Leave a Reply

//zeechumy.com/4/4998019
%d bloggers like this: