Stephen Ajagbe, Ilọrin
Ṣọọbu mẹta ọtọọtọ nile itaja nla oniyara mẹrinla kan, Abdulsalam Shopping Complex, lọna Western Reservoir, lagbegbe Ọlọrunṣogo, niluu Ilorin, ni ijamba ina to ṣẹlẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja jo.
Ninu atẹjade kan lati ọwọ alukoro ileeṣẹ panapana nipinlẹ Kwara, Ọgẹni Hassan Hakeem Adekunle, nnkan bii aago mẹjọ alẹ niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.
O ṣalaye pe ẹnikan torukọ rẹ n jẹ Kazeem lo pe ileeṣẹ naa lori foonu lalẹ iṣẹ ọhun ni nnkan bii aagọ mẹjọ kọja iṣẹju marun-un. Oju ẹsẹ lawọn si gbera lọ koju ina naa.
O ni lai fi akoko ṣofo awọn ikọ to lọ pana ọhun balẹ sibẹ laago mẹjọ kọja iṣẹju mẹwaa ti wọn si ba ina naa to n jo awọn ọja nile itaja naa.
O tẹsiwaju pe awọn tete ri ina naa pa ko si raaye tan ka awọn ṣọọbu yooku.
́O ni awọn fura pe ina mọnamọna to ṣẹju laarin awọn igun ti waya ti sopọ mọra lo ṣokunfa ijamba naa.
O ni Ọga agba ileeṣẹ panapana ni Kwara,
Alhaji Waheed I. Yakub, rọ araalu lati maa kiye sara nigba gbogbo. O gbadura ki Ọlọrun fi ọpọ rọpo fun awọn to padanu dukia wọn ninu ijamba ina naa.