Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Eeyan meji lo doloogbe lọsan-an Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 yii, awọn mejila si fara pa nigba ti ijamba ọkọ ṣẹlẹ loju ọna to lọ s’Ibadan lati Abẹokuta.
Mọto mẹta ọtọọtọ ni asidẹnti naa kan gẹgẹ bi Alukoro TRACE, Babatunde Akinbiyi, ṣe wi.
O ni ni nnkan bii aago meji ọsan kọja iṣeju mẹwaa ni lọjọ naa. Awọn mọto to kan ni bọọsi ti nọmba ẹ jẹ LSD 937 HE, mọto akero Fọọdu ti nọmba ẹ jẹ AKM 801 ZW ati tirela kan to ko ba wọn to jẹ o sa lọ ni.
Akinbiyi ṣalaye pe tirela lo jẹbi ọrọ, o ni oun lo n sare buruku to fi di pe awọn bọọsi ti ọkan n lọ s’Ibadan ti ikeji n bọ l’Abẹokuta fi fori sọra wọn, iyẹn lọgangan Abule Akankan, Ọdẹda.
Ọmọ kekere kan tọjọ ori ẹ ko ju marun-un lọ ati iyaale ile kan lo ba iṣẹlẹ yii rin, wọn ku loju-ẹsẹ ni. Awọn mejila mi-in si tun farapa.
Ileewosan Jẹnẹra Ọdẹda ni wọn ko awọn to ṣeṣe lọ, mọṣuari ibẹ naa ni wọn ko awọn oku si.