Ijamba mọto ran eeyan meje sọrun lojiji nipinlẹ Ogun

Adewale Adeoye

Ọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii, ni ijamba ọkọ meji kan waye lagbegbe Ogere, nipinlẹ Ogun, ti eeyan meje lara awọn to wa ninu asidẹnti naa si padanu ẹmi wọn, nigba tawọn bii mọkanla kan ti wọn fara pa yannayanna ninu ijamba ọhun wa lẹsẹ-kan- aye, ẹsẹ-kan-ọrun nileewosan kan to wa lagbegbe naa ti wọn ti n gba itọju bayii.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹsan-an kọja ọgbọn iṣẹju aṣaalẹ ọjọ kẹrinlelogun, oṣu  yii, ni mọto akero Mazda kan ti nọmba rẹ jẹ  ‘MNY 894 YN’ lọọ ko sabẹ  tirela kan ti ko ni nọmba idanimọ kankan lara. Ero mejilelogun ni wọn wa ninu ọkọ akero naa lasiko ti ijamba ọhun waye, ọkunrin mẹẹẹdogun ati obinrin mẹta. Ọkunrin mẹsan-an ati obinrin meji ni wọn fara pa yannayanna, nigba ti ọkunrin marun-un ati obinrin meji ku sinu ijamba ọhun.

Alukoro ajọ ẹṣọ oju popo ‘Federal Road Safety Corps’ (FRSC), ẹka tipinlẹ Ogun, Abilekọ Florence Okpe, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu yii, sọ pe ere asapajude ti dẹrẹba mọto akero Mazda naa n sa lo ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun. Bakan naa lo bu ẹnu atẹ lu bi awọn dẹrẹba ọkọ, paapaa ju lọ, awọn ọkọ akero ṣe maa n sare asapajude loju titi lasiko ti wọn ba n rinrin-ajo.

Atẹjade kan ti wọn fi sita nipa iṣẹlẹ ọhun sọ pe, ‘ijamba ọkọ kan waye laarin mọto akero Mazda kan ti nọnba rẹ jẹ MNY 894YN ati mọto tirela kan, awọn to fara pa ninu ijamba ọhun la ti gbe lọ sileewosan alaadani kan ti wọn n pe ni Patmag Hospital, to wa lagbegbe Ogere, fun itọju to peye. Bakan naa la ti gbe awọn ti wọn ku lọ si mọṣuari kan to wa nileewosan FOS, niluu Ipara, nipinlẹ Ogun.

Ọga agba ajọ ẹṣọ oju popo nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Anthony Uga, rọ awọn dẹrẹba ọkọ gbogbo pe ki wọn maa ṣe ọpọlọpọ suuru lasiko ti wọn n ba wa ọkọ loju popo.

Bakan naa lo ba ẹbi awọn to padanu eeyan wọn sinu iṣẹlẹ ọhun kẹdun. O ni o yẹ kawọn araalu paapaa maa le gba awọn dẹrẹba wọn lamọran lasiko ti wọn ba n sare asapajude ti wọn ba n wa wọn lọ.

Leave a Reply