Ijamba mọto ti paayan mẹta ni Dọpẹmu

Faith Adebọla, Eko

Ijamba ọkọ ayọkẹlẹ to ṣẹlẹ ni nnkan bii aago meji ọsan ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ti mu ẹmi eeyan mẹta lọ lẹyẹ-o-sọka nibudokọ Cement, lagbegbe Iyana Dọpẹmu, bẹẹ lawọn mẹta mi-in ṣi wa ni bi-yoo-ku bi-yoo-ye.

Ọkọ ayọkẹlẹ SUV kan la gbọ po sare asapajude, to si lọọ sọri mọ tirela to n lọ niwaju ẹ lọna marosẹ Abẹokuta si Eko, ti eyi si ti fa sun-kẹrẹ fa-kẹrẹ rẹpẹtẹ loju ọna naa, bo tilẹ jẹ pawọn ẹṣọ oju popo ti n ṣiṣẹ gfidigidi lati mu ki lilọ bibọ ọkọ sunwọn si i.

Alukoro fun ileeṣẹ to n ri si igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko (LASTMA), Ọgbẹni Olumide Filade, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o sọ pe awọn ti ko awọn oloogbe naa lọ si mọṣuari ileewosan ijọba to wa nitosi, wọn si ti ko awọn to fara gbọgbẹ lọ sọsibitu pẹlu.

Leave a Reply