Ijamba ọkọ ajagbe elepo fẹmi ọpọ eeyan ṣofo l’Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ 

Eeyan mẹrin ni wọn pade iku ojiji, ti ọpọ eeyan si tun fara pa nibi ijamba ọkọ ajagbe kan to waye niluu Ikarẹ-Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Ila-Oorun Akoko, lọsan-an ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii.

ALAROYE gbọ pe ilu Ọgbagi Akoko ni awakọ naa ti n bọ pẹlu epo diisu to wa ninu ọkọ rẹ.

Oke nla kan to wa laduugbo Ọkọrun, Ọlọkọ, n’Ikarẹ Akoko, ni wọn lo n sọ kalẹ lọwọ to fi padanu ijanu ọkọ rẹ, leyii to ṣokunfa bo ṣe lọọ kọ lu awọn ọkọ, ọlọkada awọn ṣọọbu atawọn to n fẹsẹ rin lagbegbe ọhun.

Awọn oiṣẹ ajọ oju popo to wa niluu ọhun la gbọ pe wọn gbiyanju ati yọ awọn to ha sabẹ ọkọ ajagbe naa, ti wọn si sare ko awọn to farapa atawọn to ku sinu iṣẹlẹ naa lọ sile-iwaosan ijọba to wa n’Ikarẹ.

Awọn fọto ijamba naa niyi:

Leave a Reply