Ijinigbe: Dapọ Abiọdun ati Makinde bẹrẹ ajọṣe lori aabo marosẹ Eko s’Ibadan

Gbenga Amos, Ogun

Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ti ni agan lọrọ awọn ajinigbe ti wọn fẹẹ sọ ọna marosẹ Eko s’Ibadan di ojuko iṣẹẹbi wọn, afi ki gbogbo wa jọ mojuto o, eyi lo mu koun ati Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, pa ọrọ oṣelu ati ẹgbẹ oṣelu ọtọọtọ tawọn wa ti, tawọn si jọ gbe ikọ alaabo bii ọgbọn kalẹ lati maa patiroolu kaakiri titi marosẹ ọhun, o lawọn o si ti i duro, oriṣiiriṣii ọgbọn ati eto aabo n lọ labẹnu.

Dapọ Abiọdun sọrọ yii l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kọkanla, ọdun yii, lasiko to ba awọn lọgaa-lọgaa ileeṣẹ iweeroyin kan sọrọ lọfiisi rẹ.

Gomina naa ni yatọ si awọn ọlọpaa, awọn ẹṣọ alaabo mi-in bii ọlọpaa-inu (DSS), ẹṣọ Amọtẹkun, Sifu Difẹnsi, So-Safe, atawọn Fijilante, lati ipinlẹ mejeeji wa lara awọn ikọ alaabo ti wọn gbe kalẹ ọhun.

O tun lawọn maa lo imọ ẹrọ igbalode bii kamẹra oju ofurufu ti wọn n pe ni duroonu (drones),  atawọn kamẹra atanilolobo mi-in bii CCTV, tori aja iwoyi lo mọ ehoro iwoyi i le.

“A o fi mọ nibẹ o, a ti bẹrẹ si i roko ẹgbẹẹgbẹ ọna marosẹ ọhun, tori palapala awọn oniṣẹẹbi yii, ti wọn aa lugọ pamọ sẹgbẹẹ igbo eti-ọna, ti wọn aa kan deede yọ jade ganboro, wọn aa ji-i-yan gbe, wọn aa tun mori mu sinu igbo. A ti ba awọn agbaṣẹṣe wa sọrọ, ki wọn ro oko ẹgbẹẹgbẹ titi naa sẹyin ni nnkan bii aadọta mita (50 meters), tọtun-tosi ni wọn maa ro, ko ni i saaye fẹnikan lati fi igbo boju ṣọṣẹ, latọọkan leeyan yoo ti ri nnkan to n ṣẹlẹ niwaju ati lẹgbẹẹgbẹ ọna kedere, ibaa jẹ lalẹ.

Awọn kamẹra oju ofurufu (drones) ta a fẹẹ lo, wọn lagbara gan-an, wọn maa sọ pato ibi ti eeyan ba wa, eyi maa jẹ ka tete mọ pato ohun to n ṣẹlẹ nibi kan, ṣaaju kawọn ajinigbe si too jade, aa ti ri wọn,” gẹgẹ bo ṣe wi.

Tẹ o ba gbagbe, ọpọ araalu lo ti n kọminu si iṣẹlẹ ijinigbe gbowo to n waye lemọlemọ loju ọna marosẹ Eko si Ibadan lẹnu ọjọ mẹta yii.

Bakan naa ni wọn n bẹru nipa iwa laabi oju ọna naa, agaga bi pọpọṣinṣin ọdun Keresi atawọn ayẹyẹ mi-in ṣe wọle de tan yii.

Leave a Reply