Ijiya nla n duro de awọn to n ta owo Naira atawọn to n lo o nilokulo-Emefiele

Monisọla Saka

Bi awọn banki ilẹ wa ba tẹle aṣẹ ti olori banki apapọ ilẹ wa, Godwin Emefiele, pa, o ṣee ṣe ki wahala ati ri owo gba ni banki to gba gbogbo ilu kan dopin. Eyi ko sẹyin aṣẹ ti ọkunrin naa pa pe ki gbogbo awọn ileefowopamọ bẹrẹ si i san owo tuntun na lori kanta wọn.

Igbesẹ yii yoo fopin si bawọn eeyan ṣe n lo pupọ akoko wọn, ti wọn si tun n ja ija ajaku akata nidii ẹrọ to n pọwo, ATM, jake-jado orilẹ-ede Naijiria. Ṣugbọn o, owo ti ẹnikọọkan le ri gba ko gbọdọ ju ẹgbẹrun lọna ogun Naira, (20,000) lojumọ.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ keji, oṣu Keji, ọdun yii, ni ọga agba banki apapọ ilẹ wa, Godwin Emefiele, sọrọ naa niluu Abuja.

Bakan naa ni wọn sọ pe awọn yoo fọwọsowọpọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ yii, atawọn ileeṣẹ mi-in tọrọ kan, lati fofin de awọn ti wọn n ta owo Naira atawọn ti wọn n lo o nilokulo.

Ninu atẹjade ti adari eto iroyin fun banki apapọ ilẹ wa, Osita Nwanisobi, fi lede lo ti sọ pe, “Olori banki to ga ju lọ nilẹ yii, Godwin Emefiele, ti paṣẹ fawọn ile ifowopamọ pe ki wọn maa san owo Naira tuntun fawọn eeyan, ati pe owo tawọn ileefowopamọ yoo ba san fawọn onibaara wọn ko gbọdọ ju ẹgbẹrun lọna ogun Naira lọ, fun ẹyọ ẹni kan ṣoṣo ninu awọn banki”.

O sọ siwaju si i pe lati le ribi pin awọn owo Naira tuntun yii sawọn banki kaakiri ilẹ yii, banki apapọ ilẹ wa rọ awọn ọmọ Naijiria, lati ṣe ọpọlọpọ suuru fawọn gẹgẹ bawọn ṣe n ṣiṣẹ takuntakun lati koju iṣoro awọn ero to maa n pọ nidii ẹrọ ATM. Bakan naa ni wọn tun ni awọn n dọdẹ awọn ti wọn n ta owo Naira ti wọn ṣẹṣẹ tun ṣe, atawọn ti wọn n lo owo naa nilokulo pẹlu bi wọn ṣe n fọn ọn danu ti wọn si n tẹ ẹ mọlẹ lawọn ode ayẹyẹ gbogbo.

O ni awọn ṣakiyesi bawọn eeyan ṣe n to si idi ẹrọ ATM kaakiri orilẹ-ede yii, ati bi awọn eeyan ṣe lọ n ko owo tuntun ti wọn ba ri gba lẹnu ẹrọ ATM pamọ, fun idi tẹnikẹni ko mọ.

Bẹẹ lo tun mẹnu ba awọn ti wọn ko forukọ silẹ, ti wọn ko si ni asunwọn ileefowopamọ kankan, ṣugbọn ti wọn n paarọ owo fawọn araalu, pẹlu irọ pe CBN lawọn n ṣe e fun, eyi to ni o n kọ aọn lominu.

O ni, “Banki apapọ ilẹ wa ti n gbe igbesẹ bayii lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn ti wọn maa n ṣe owo Naira baṣubaṣu lawọn ode ayẹyẹ. Iwa aibofinmu ni keeyan maa ta owo Naira, fọn ọn danu nibi ti wọn ba lawọn ti n na an lode, abi ki wọn maa tẹ ẹ mọlẹ labẹ bo ti wu ko mọ. Iru awọn eeyan bẹẹ ki i ṣe ọmọ orilẹ-ede Naijiria tootọ, tori wọn ko nifẹẹ ilu wọn lọkan. Lati wa ọwọ iwa ainifẹẹ ilu ẹni lọkan yii bọlẹ, banki apapọ ti fẹẹ fọwọsowọpọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa, ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ owo-ori, FIRS, ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, EFCC, ati eyi to n ri si ọrọ owo-ìná, NFIU.

‘‘Ọkan lara ami idamọ orilẹ-ede yii ni owo ti awọn kan n ṣe bo ṣe wu wọn yii. Agbẹnusọ banki apapọ ilẹ wa waa rọ awọn ọmọ Naijiria lati maa ṣamulo awọn ọna ka-ta-ka-ra ati inawo ti ko ni i ṣe pẹlu nina owo beba.

Leave a Reply