Ijọba bẹrẹ oogun ọfẹ fawọn ẹlẹwọn atawọn ara ipinlẹ Ọyọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ṣinkin ni inu awọn ẹlẹwọn to mọ rírì ilera n dun bayii pẹlu bi ijọba ipinlẹ Ọyọ ti ṣe gbe iwosan ọfẹ lọọ ka wọn mọnu ọgba ẹwọn nibẹ.

Ninu eto ilera ọfẹ ọhun ni wọn ti n fun awọn ẹlẹwọn atawọn afurasi ọdaran ti wọn fi si ahamọ ọgba ẹwọn loogun ọfẹ ati abẹrẹ ajẹsara ọfẹ fun iba koju-pọn ati arun yinrunyinrun.

Ijọba ipinlẹ Ọyọ, pẹlu ajọṣepọ ajọ to n fopin si ipenija awọn ọmọde lagbaaye, iyẹn United Nations International Children Emmergency Fund (UNICEF) lo ṣagbatẹru eto ọhun, eyi to bẹrẹ  l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, ti yoo si wa sopin lojọ Aiku, Sannde, ọjọ kejila, oṣu kejila, ọdun yii.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ nipa eto yii n’Ibadan, aṣoju ajọ UNICEF, Abilekọ Amina Yahyah, sọ pe ọpọlọpọ ibudo lawọn eeyan yoo ti lanfaani lati maa gba abẹrẹ ajesara ati oogun ọfẹ fun idena aisan iba koju-pọn atarun yinrunyinrun.

Awọn akọṣẹmọṣẹ eleto ilera to fẹẹ to ẹgbẹrun mẹta lo ni ijọba gbe iṣẹ naa le lọwọ, gbogbo ileewe ijọba ati taladaani, bẹrẹ lati ileewe alakọọbẹrẹ titi de ileewe giga bii poli ati fasiti ni wọn yoo si pin oogun ọfẹ ọhun de.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “A ti kọ lẹta sawọn oludasilẹ ileewe aladaani gbogbo ni ipinlẹ yii lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn eleto ilera to ba n ṣiṣẹ yii.

Ninu ọrọ tiẹ, Dokita Olukorede Ikumme to jẹ alamoojuto awọn iṣẹ pajawiri fun ileeṣẹ eto ilera ijọba ipinlẹ Ọyọ sọ pe arun awọn ọmọde larun yinrunyinrun, nigba ti iba koju-pọn le mu ọmọde titi dori agbalagba ti ko ti i ju ẹni ọdun mẹrinlelogoji (44) lọ.

O ni ọdun mẹwaa labẹrẹ ajẹsara ti wọn n fun awọn eeyan lati dena arun yinrunyinrun yoo fi ṣiṣẹ lara awọn eeyan ti wọn ba fun.

O waa rọ awọn obi lati gba ọmọ wọn laaye lati gba abẹrẹ ajẹsara naa nitori anfaani ilera wọn.

Leave a Reply