Ijọba ti ileegbafẹ Ventura pa n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti ba ariya opin ọsẹ yii jẹ fun ọpọ awọn alafẹ igboro ilu Ibadan pẹlu bi wọn ṣe ti Ventura, ile igbafẹ kan to gbaju gbaja n’Ibadan pa.

Ventura, ile gogoro alaranbara to wa lọna Samọnda, lagbegbe Sango, n’Ibadan, lawọn to fẹran ariya ti maa n ṣe faaji lojoojumọ pẹlu ere sinima wiwo, ayo tita atawọn nnkan faaji mi-in.

Ijakulẹ ti ko jọ pe awọn alafẹ to maa n ba wọn dowo-pọ ri ri ni wọn ba pade lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọse to kọja, nigba ti wọn ba ile igbafẹ to maa n kun fọfọ férò ni tọsan toru yii ni titi gbọingbọin, wọn ko mọ pe lati aarọ ọjọ naa nijọba ti ti abawọle sile igbafẹ ọhun.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ẹka ijọba ipinlẹ Ọyọ to n ṣamojuto eto ayika atawọn ohun alumọọni lo ti ile ariya naa pa laaarọ ọjọ Ẹti.

Ẹsun iwa ọbun nijọba fi kan awọn alakooso Ventura, wọn ni wọn ko ṣeto bi awọn omi idọti ti wọn n lo nileegbafẹ to gbajugbaja yii yoo ṣe maa wọnu ilẹ lọ, niṣe ni gbogbo omi ẹgbin wọn nibẹ n ṣan si oju agbara, eyi to lodi si ofin ijọba to ni i ṣe pẹlu eto imọtoto ayika ati ilera araalu.

Pẹlu bi Ventura ṣe wa ni titi ta a fi pari akojọ iroyin yii, ọpọ awọn ti ko ti i gbọ nipa sẹria ti ijọba da fun wọn ni wọn ti n debẹ tan ki wọn too pada sile tabi gba ibomi-in lọ nigba ti wọn ko raaye wọle lọọ ṣe faaji ti wọn feran lati maa ṣe nibẹ tẹlẹ.

Leave a Reply