Ijọ Ridiimu fẹẹ gba awẹ ọgbọn ọjọ fun alaafia Naijiria

Jide Alabi

Ki alaafia le pada si orilẹ-ede Naijiria, Olori ijọ Ridiimu, Pasitọ Enoch Adeboye, ti ke si awọn ọmọ ijọ ẹ lati gba aawẹ ọgbọn ọjọ.

Pasitọ Johson Ọdẹṣọla ti i ṣe amugbalẹgbẹẹ fun olori ijọ yii lo sọrọ ọhun niluu Ibadan, lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

O ni Alagba Adeboye ti sọ pe ọjọ ki-in-ni, oṣu kọkanla, ọdun yii, ni gbogbo Kristẹni ti wọn jẹ ọmọ ijọ Ridiimu gbọdọ bẹrẹ aawẹ ati adura ọhun fun Naijiria.

O fi kun un pe laarin ọjọ kin-in-ni, si ikẹrinla, ni aawẹ agbayipo yoo waye fawọn ti wọn ba lanfaani lati gba a, ti eto bi ohun gbogbo yoo ṣe lọ yoo tẹ wọn lọwọ laipẹ yii.

Bakan naa lo rọ awọn ọmọ ijọ ọhun lati wa fun ipade adura, ati pe gbogbo eto ati ilana ti ijọba la kalẹ lori iparamọ lati dena itankalẹ arun koronafairọọsi lawọn yoo tẹle.

Pasitọ Johnson Ọdẹṣọla tun sọ pe Alagba Adeboye ti ni ki awọn sọ fun gbogbo awọn ọmọ ijọ naa ki wọn gbiyanju lati fadura ati aawẹ ọlọgbọn-ọjọ yii jagun fun alaafia Naijiria.

 

Leave a Reply