Faith Adebọla, Eko
Bi ko ba ṣe’ni ri, a ki i sọ pe o tun de si’ni, gẹgẹ bii owe Yoruba, ijọba ipinlẹ Eko ti ṣekilọ fawọn olugbe ipinlẹ naa pe ki wọn ṣọra fun ewu akunya odo ati iṣẹlẹ omiyale lọdun yii, tori nnkan bii oṣu mẹwaa tabi ko din diẹ, lojo yoo fi rọ nipinlẹ naa lọdun 2022.
Ijọba ni afaimọ ni ki ayipada to de ba oju-ọjọ ati ayika ma mu ki ọwara ojo tọdun yii legba kan ju ti eṣi lọ.
Nibi apero kan pẹlu awọn oniroyin to da lori asọtẹlẹ oju-ọjọ lọdun 2022, eyi to waye lopin ọsẹ yii nile ijọba Eko, ni Alausa, Ikẹja, lọrọ naa ti jẹ yọ.
Kọmiṣanna fun eto ayika ati ipese omi nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Tunji Bello, sọ pe ajọ to n ri si ayipada oju-ọjọ (NiMET) maa n sasọtẹlẹ bi ojo yoo ṣe pọ tabi kere to lati ibẹrẹ ọdun, bi ooru yoo ṣe wa si jake-jado orileede wa, akojọpọ asọtẹlẹ wọn si lawọn maa n tẹle ninu awọn atẹjade ijọba.
O ni asọtẹlẹ naa maa n ṣanfaani fawọn agbẹ, awọn to n gbero lati ṣiṣẹ ode, titi kan awọn olokoowo, ati ileeṣẹ ijọba gbogbo, tori ṣaaṣa ni ọrọ ojo ati oorun ko kan.
O ni asọtẹlẹ ojo fun ipinlẹ Eko fihan pe lati nnkan bii ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta, si ipari oṣu kẹsan-an, tabi aarin meji oṣu Kẹwaa, ọdun yii, lawọn araalu yoo fi gbalejo ejiwọwọ ati ọwara ojo.
Ṣugbọn o fawọn eeyan lọkan balẹ pe ijọba ti wa ni igbaradi lati koju iṣoro omiyale to le ṣẹlẹ nigba tawọn odo ba kun akunya.
Bakan naa ni Oludamọran fun gomina lori ipese omi ati koto idaminu, Ẹnjinnia Joe Igbokwe, sọ pe iṣoro aabo to mẹhẹ lawọn agbegbe kan lorileede yii ti mu ki iye eeyan to n rọ wọlu Eko pọ si i, aini nnkan amayedẹrun si ti pọ si i.
O rọ araalu lati ṣatilẹyin fun ijọba nipa kiko idọti kuro ninu gọta iwaju ile wọn, ki wọn si ma ṣe maa sọ awọn ike, igo, agolo atawọn nnkan to le dena ọgbara sinu awọn gọta naa.
Bakan naa lo ṣekilọ fawọn olugbe agbegbe ti omiyale ti maa n yọ wọn lẹnu lọdọọdun bii Iwaya, Makoko, Ijọra Badiya, Agboyi Ketu, Itowolo, Iṣẹri, ati awọn ti wọn kọle sitosi odo lati wa lojufo, tori oju lalakan fi n ṣọri.