Ijọba ṣekilọ: Ẹni to ba kọ lati lo ibomu l’Ekoo le fẹwọn jura o

Faith Adebọla, Eko

Ijọba ipinlẹ Eko ti kilọ pe kawọn eeyan ma ṣe ro pe ṣereṣere ni ọrọ pipa eewọ itankalẹ Korona mọ nipinlẹ naa, paapaa lori ọrọ lilo ibomu, wọn ni ẹni to ba kọ lati lo ibomu ṣetan lati fẹwọn jura ni.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, nijọba fi ikilọ ọhun sode lori atẹ agbọrọkaye ijọba ipinlẹ Eko, lorukọ Gomina Babajide Sanwo-Olu. Wọn ni ki ẹni ti ko ba ti i mọ tẹlẹ tete mọ bayii pe iwa arufin ni fẹnikẹni lati jade sigboro lai lo ibomu, tabi awọn to maa n wọ ọ lọna ti ko yẹ.

“Njẹ o mọ pe teeyan ba kọ lati wọ ibomu laarin ero tabi ni gbangba, tabi teeyan ṣẹ si awọn alakalẹ ijọba lori ati dena arankalẹ arun COVID-19, ijọba maa mu onitọhun, wọn yoo si ba a ṣẹjọ nibaamu pẹlu ofin igbogun-ti ajakalẹ arun l’Ekoo (Lagos State Infectious Diseases (Prevention) Regulations ti wọn tun ṣe lọdun 2020, tabi labẹ ofin iwa ọdaran tipinlẹ Eko n lo, tọdun 2015.”

Wọn ni ẹni to ba jẹbi le sanwo itanran tabi ki wọn ni ko ṣiṣẹ sin’lu lafikun, wọn si le ran ẹni naa lẹwọn taarata.

Tẹ o ba gbagbe, arun Korona tun ti n gberu lẹẹkeji nipinlẹ Eko lasiko yii. Gomina Sanwo-Olu funra rẹ lugbadi arun ọhun, o ṣi wa nile rẹ gẹgẹ bii ẹni ayasọtọ, bo tilẹ jẹ pe wọn lo ti n gbadun daadaa pẹlu itọju ati oogun ti wọn n fun un.

Leave a Reply