Ijọba ṣi n wa awọn ẹlẹwọn bii ẹgbẹta to sa kuro l’Ọyọọ

Jọkẹ Amọri

 Minisita fun ọrọ abẹle lorileede yii, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ti rọ awọn araalu pe ki wọn maa ba gbogbo ohun ti wọn ba n ṣe lọ, ko sewu kankan mọ lori ọrọ awọn agbebọn kan to ya bo ọgba ẹwọn to wa ni Abolongo, niluu Ọyọ, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejilelogun, oṣu yii.

Agbẹnusọ fun Arẹgbẹ lori eto iroyin, Ṣọla Fasure, lo sọrọ naa niluu Abuja nigba to n fesi lori iṣẹlẹ naa.

O ni loootọ ni ọga oun ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ti awọn lọgaa lọgaa tọrọ kan si ti bẹrẹ iṣẹ loju-ẹsẹ lati ri i pe ohun gbogbo wa bo ṣe yẹ.

Yatọ si eyi, o ni wọn ti ri awọn ẹlẹwọn bii ọtalenigba ati meji (262) mu, ti wọn si ti pada sinu ọgba ẹwọn naa. Awọn to din diẹ ni ẹgbẹta (575) lo ni wọn ti mori mu, ṣugbọn tijọba apapọ ti n gbe igbesẹ lati ri wọn mu.

Bakan naa lo rọ awọn araalu pe ki wọn wa lojufo, ki wọn si maa ṣakiyesi awọn ti wọn ba n rin gberegbere kiri adugbo, tabi awọn ti irin wọn ko ba mọ. O ni ki wọn fi to awọn agbofinro leti bi wọn ba ti ri iru awọn eeyan bẹẹ.

Nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ ọjọ Ẹti ni awọn agbebọn kan ya bo ọgba ẹwọn Abolongo, to wa ni Oriawo, niluu

Ọyọ, ti wọn si tu awọn ẹlẹwọn kan silẹ. Lasiko ti awọn eeyan naa tawọn oluṣọ ọgba ẹwọn ọhun doju ibọn kọra wọn lawọn ẹlẹwọn kan sa lọ, tawọn kan si fara pa.

Leave a Reply