Ijọba aditi ati odi nijọba asiko yii – Fayoṣe

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayọdele Fayoṣe, ti sọ pe oun ko si lara awọn to maa bu Aṣiwaju Bola Tinubu tẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) nitori ojulowo ọmọ Yoruba ni, o si ti ṣe awọn nnkan iwuri lati ran awọn eeyan lọwọ. Bakan naa lo ni oun ko ba Gomina Ṣeyi Makinde tipinlẹ Ọyọ ja si ipo tabi agbara nitori idagbasoke ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP) lo jẹ oun logun.

Fayoṣe sọrọ yii lopin ọsẹ to kọja nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lori ayajọ ọgọta ọdun to ṣe atawọn nnkan to n ṣẹlẹ lagbo oṣelu lọwọlọwọ.

Gomina tẹlẹ naa ni ọpọ ninu awọn ti Tinubu sọ di eeyan nla, ti wọn si ti di baba isalẹ lagbo oṣelu lo ti kọyin si agba oloṣelu naa, ṣugbọn oun ko ni i sọrọ ẹ laidaa tabi ba wọn duro sibi ti wọn ti n ditẹ ẹ, bo tilẹ jẹ pe awọn ko si lẹgbẹ oṣelu kan naa, ti ko si ran oun lọwọ lagbo oṣelu.

Fayoṣe ni, ‘‘Mo duro lori nnkan ti mo sọ, ṣugbọn eyi ko tumọ si pe mo n ṣe atilẹyin fun un. Ẹ wo Buhari, nigba ti aunti mi ku, o ba mi kẹdun, ṣugbọn iyẹn ko sọ pe ọrẹ ni wa. Lẹyin igba to ṣe iyẹn, mo ti fi ẹsun oriṣiiriṣii kan an lori bo ṣe n ṣejọba.

‘‘Ẹ jẹ ki n sọ ọ ki gbogbo aye le gbọ: mi o ki n ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, mi o si ni i di ọmọ ẹgbẹ naa laelae. Mo ṣatilẹyin fun Fayẹmi lati di gomina nipasẹ Tinubu nigba kan ri, ṣugbọn iyẹn ko sọ pe mo maa darapọ mọ ẹgbẹ wọn. Ti oṣelu ko ba ṣee ṣe mọ, mo maa pada sile lati lọọ ṣe ọkọ iyawo mi ati baba awọn ọmọ mi.’’

Lori ọrọ ija to n lọ laarin oun ati Ṣeyi Makinde, Fayoṣe ni oun ko ba gomina naa ja nitori ko si agbara tawọn n ja si, ipinlẹ kọọkan lo si ni agbekalẹ oṣelu tiẹ ninu ẹgbẹ PDP.

‘‘Ko si agbara kankan ta a n ja si nitori ko si ijọba ilẹ Yoruba, ijọba ipinlẹ lo wa. Ti emi ati Gomina Makinde ba tiẹ ni nnkan ta a n fa, kawọn eeyan ma daamu ara wọn, ọrọ oṣelu lasan ni.

‘‘Emi ni mo lọọ ṣefilọlẹ ibẹrẹ ipolongo ẹ niluu Ogbomọṣọ, nitori naa, kin ni idunnu mi to ba ṣubu tabi to kuna? Adura mi ni pe yoo ṣaṣeyọri. Nnkan to n ṣelẹ, awọn to n tẹle wa lo jẹ ko ri bo ṣe ri.

‘‘Pe boya Gomian Makinde n ṣatilẹyin fun Sẹnetọ Biọdun Olujimi tabi bẹẹ kọ, iyẹn kọ ni koko. A ti ṣe ibo ẹgbẹ, awọn Olujimi ti gba ile-ẹjọ lọ. Ti Olujimi ba yege ni kootu, mo maa ṣatilẹyin fun un; to ba jẹ idakeji naa, ki wọn dara pọ mọ wa lati gbe ẹgbẹ PDP soke.’’

Lori ọrọ gomina ipinlẹ Ebonyi to lọ si APC, Fayoṣe ni awọn oloṣelu to n wa nnkan ti wọn maa jẹ kiri lo pọ lagbo oṣelu, wọn ko si ni afojusun kankan. O ni ti ẹnikan ba jale, to si dara pọ mọ APC, kia ni wọn maa gba a, ti yoo si maa gbadun lọdọ wọn.

O waa bẹnu atẹ lu ipo ti ilẹ Naijiria wa lọwọlọwọ, o ni ebi ti di baraku fawọn ọmọ ilẹ yii, bẹẹ ni ko si eto aabo, Aarẹ Muhammadu Buhari gan-an ko si ṣetan lati gba iṣẹ lọwọ awọn ọga ṣọja ati ọlọpaa, idi niyi toun fi n pe ijọba asiko yii ni ijọba aditi ati odi.

Leave a Reply