Ijọba Alaafin Lamidi  Ọlayiwọla Adeyẹmi (1971 – 2022) (1)

Wọn gbade kari ọba tuntun, Adeyẹmi Kẹta si ṣeleri pe igba toun yoo tu gbogbo ilu lara

Fun ọpọlọpọ oṣu lẹyin ti wọn gbe ade kari Lamidi Ọlayiwọla Atanda Adeyẹmi, to pada di Alaafin tootọ lẹyin gbogbo rogbodiyan to ti kọja lọ, ko si ọmọ Ọyọ kan to gbagbe awọn iṣẹlẹ naa, nitori rẹ lo ṣe jẹ inu ayọ ati idunnu ni gbogbo wọn wa ni ọpọ igba naa, ti wọn si n ṣe ọba wọn yii bii iyawo tuntun. Ta ni yoo ṣe! Ọba ti wọn ti kede rẹ lati ọdun 1968, ti wọn ko si jẹ ki ade de ori ẹ titi di ibẹrẹ ọdun 1971. Ọmọ ọgbọn ọdun lo wa nigba ti wọn kede orukọ rẹ pe oun ni yoo jọba, ṣugbọn ọmọ ọdun mejilelọgbọn lo ti pe nigba ti ade too kan an lori, bi ko si jẹ pe Ọlọrun ti kọ ade naa mọ ọn ni, ko si bi kinni naa yoo ṣe de ori rẹ laelae. Awọn alatako dide, wọn ni ipo naa ko tọ si i, ọrọ naa di tawọn oloṣelu, awọn naa binu titi, wọn si ji ija atijọ dide, ṣugbọn nigbẹyin, aaro kan ki i gbona janjan ko ma rọlẹ, Lamidi Atanda pada waa di Alaafin.

Lẹyin ti wọn si ti ṣe ariya tan. Alaafin ko jokoo kẹtẹnfẹ, oun naa ni aaya ti bẹ silẹ bẹ sare, pe iṣẹ idagbasoke ilu Ọyọ loun yoo fi bẹrẹ iṣẹ oun. Ṣugbọn iṣẹ idagbasoke kan ko ṣee ṣe nibi ti Ọyọ wa nigba ti Lamidi Adeyẹmi di ọba wọn. Ko si si ohun meji to fa a naa ju ija to wa nilẹ lọ, ija bi wọn ko ṣe gbe ade ka ori Sanda Ladepo ọmọ Ọranlọla, to jẹ ori Layiwọla ni wọn gbe e ka. Ko si si ohun meji to jẹ ki ija naa tubọ maa le si i naa ju pe awọn oloṣelu ti ti ọwọ bọ ọ, wọn ti ẹsẹ bọ ọ, koda wọn ki gbogbo ara si i. Ija awọn ọmọ ẹgbẹ NCNC ati awọn ọmọ ẹgbẹ Action Group naa ni. Inu gbogbo ọmọ ẹgbẹ Ọlọpẹ ko dun rara si bi ọrọ naa ti pada ja si, koda lẹyin ti ijọba ti fofin ija kootu de wọn, ti wọn si gbe ade kari ọba naa, ija naa ko tan ninu wọn. Wọn n reti pe ohun iyanu kan yoo ṣẹlẹ lojiji, ti yoo fun awọn laaye lati tun pada sidii ẹjọ ti awọn n ṣe bọ.

Ẹni ti ko ba ni i jẹ ki a jẹun yo, eeyan yoo tete kọ tirẹ mọ ọka ni;’ Alaafin Adeyẹmi mọ eyi, nitori bẹẹ lo ṣe tete mura si irin rẹ ni gbara to ti gbajọba. Ohun to n sọ ni pe oun fẹ ki ija Ọyọ tete pari. O ranṣẹ si awọn ti wọn n ba a ja ti wọn jẹ ọmọ idile kan naa pelu wọn, o ni ọba ti jẹ, ki kaluku gbaruku ti ọba lo ku, ki wọn gbagbe ọrọ ana, ki wọn le ri ẹni ba ṣere. Awọn pupọ ni wọn gbọ ipe yii ti wọn wa, awọn mi-in tilẹ ti wa ko too di pe  Alaafin jẹ rara, ṣugbọn awọn ti wọn pada wa lẹyin ti ọba ti jẹ ju awọn ti wọn wa tẹlẹ lọ.  Ṣugbọn awọn ti ọrọ naa kan gan-an ko wa, Ọranlọla ati baba rẹ ko de aafin, ati awọn diẹ mi-in ti wọn ko gba pe ipo Alaafin ọhun ti bọ lọwọ awọn. Wọn n reti pe kinni kan yoo  ṣẹlẹ, awọn oloṣelu si n ki wọn laya pe ijọba mi-in n bọ, wọn ni wọn ko ni i  pẹẹ gbe Adeyinka Adebayọ lọ. Wọn ni ti wọn ba ti gbe Adebayọ kuro ti wọn gbe gomina mi-in wa, ẹjọ naa yoo bẹrẹ lakọtun ni.

Ohun ti awọn yii ṣe n wi bẹẹ ni pe wọn ti gbọ hunrunhunrun pe ijọba Yakubu Gowon fẹẹ yọ awọn gomina ti wọn ti n lo bọ lati ọjọ yii, pe wọn yoo gbe gomina tuntun si i, ati pe o ṣee ṣe ki awọn gomina tuntun naa yan awọn kọmiṣanna ti wọn maa jẹ ẹni to maa gbọ ọrọ si awọn lẹnu, ti wọn yoo jẹ ki awọn maa ṣe ẹjọ ti awọn n ṣe yẹn lọ, pe ti awọn ba ti n ṣe ẹjọ naa lọ, awọn yoo pada bori ni. Igbagbọ wọn ni pe ti Sanda Ọranlọla ba fi le di Alaafin, abuku ko ni i kan ẹgbẹ awọn ni ilu Ọyọ, ohun ti awọn ba si fẹ ni Alaafin naa yoo maa ṣe. Ṣe ẹgbẹ Action Group; lo fi Bello Gbadegẹṣin Ladigbolu Keji jẹ, wọn si lo ọba naa daadaa lati tubọ fi abuku kan Adeniran Adeyẹmi ti wọn yọ kuro nipo ọba. Ọpọlọpọ igba ni Gbadegẹṣin kọwe si awọn ijọba Western  Region igba naa pe Adeniran ti gbe ade ati ọpa aṣẹ lọ, ko si fi awọn nnkan oye ti oun yoo lo bii Alaafin silẹ.

Ọrọ yii bi Ige, o bi Adubi nigba naa, ṣugbọn nigbẹyin, lẹyin iwadii awọn akọwe ijọba gbogbo, wọn ri i pe awọn ohun ti Gbadegẹṣin n sọ pe Adeniran lo ko lọ yii, gbogbo ẹ lo wa ninu aafin. Awọn akọwe ijọba igba naa wa lati waa ja ilẹkun loju ọlọpaa ati awọn ọmọ oye mi-in, ki wọn too ṣẹṣẹ waa kẹru to jẹ ti Alaafin Adeniran Adeyẹmi jade, nitori ọba naa ko mu ohunkohun jade niluu Ọyọ nigba to n lọ. Gbogbo bi Gbadegẹṣin si ti n ṣe eleyii ni inu awọn ti wọn n tẹle e n dun, wọn ni bo ti yẹ ko ri fun Adeniran ree, nitori o ti fi oju ẹgbẹ Ọlọpẹ gbolẹ, iya yoowu to ba si jẹ ẹ, ohun to tọ si i ni. Awọn ero to fẹ ti Gbadegẹṣin yii, awọn ọmọ ẹgbẹ Ọlọpẹ ni wọn, awọn ti wọn n jo ijo ayọ pe oju ti ti awọn ẹgbẹ Parapọ, awọn ẹgbẹ NCNC, pe wọn ti rẹyin wọn. Awọn naa ni wọn wa nidii ọrọ atako Lamidi Adeyẹmi yii, ti wọn si mura si ija naa kankan.

Ọrọ naa le ni ilu Ọyọ yii nigba naa to jẹ ọtọọtọ lawọn eeyan n kirun ni Mọṣalaaṣi Jimọ, nitori mọṣalaaṣi apapọ (Central Mosque) meji lo wa, eyi ni pe Lemọmu agba ilu Ọyọ meji lo wa, kaluku si ni baba ninu mọṣalaaaṣi rẹ. Yatọ si eyi, ọna meji ni wọn ti n kirun yidi. Bi ọdun Ileya ba de, tabi ọdun Itunu-aawẹ, Yidi meji ni awọn eeyan naa yoo lọ. Awọn ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ Ọlọpẹ ati awọn oloṣelu to fara mọ wọn pẹlu awọn eeyan wọn, Yidi ọtọ ni wọn n lọ, awọn ti wọn si jẹ ọmọ Ẹgbẹ NCNC ati parapọ naa, Yidi ọtọ ni wọn n lọ, bẹẹ ọmọ Ọyọ kan naa ni gbogbo wọn. Ọrọ naa le ju bẹẹ lọ o. Bi awọn ọmọde meji ba wa ti wọn fẹran ara wọn, iyẹn wundia ati bọisi, ti wọn si n gbero lati fẹ ara wọn sile bii tọkọ-taya, afi ki awọn baba wọn wa ninu ẹgbẹ oṣelu kan naa o, bi bẹẹ kọ, bi awọn mejeeji ba fi tipa tipa fẹ ara wọn, awọn baba naa yoo lọọ mu ọmọ wọn kuro nile ọkọ ẹ, wọn aa ni ko ṣee ṣe.

Ohun to si mu ọrọ naa maa dun awọn eeyan nigba naa ni pe ijọba ologun ti fofin de oṣelu ati gbogbo awọn ẹgbẹ to n ṣe e, ṣugbọn kinni naa ko tan ni Ọyọ, ati ilẹ Yoruba lapapọ, awọn ti wọn wa ninu ẹgbẹ Ọlọpẹ, ti wọn jẹ ọmọlẹyin Awolọwọ ta ku pata, wọn ni awọn ko ni i ba ọmọ ẹgbẹ NCNC to jẹ ti Azikiwe, tabi awọn ti Dẹmo to jẹ ti Akintọla ṣe. Bẹẹ naa lawọn ọmọ ẹgbẹ mejeeji yii naa taku, ohun gbogbo to ba ti jẹ ti ẹni yoowu to ti ṣe ẹgbẹ Ọlọpẹ tẹlẹ ri, wọn yoo jinna si i ni. Ohun to si jẹ ki ija naa le koko laarin ọdun 1970 si 1971 yii ni pe ogun ti pari. Ogun Ojukwu ti wọn n ja nigba naa ti pari ninu oṣu Kin-in-ni, ọdun 1970, awọn eeyan yii si ti n fọkan si i pe ọga ologun Yakubu Gowon to n ṣejọba nigba naa ko ni i pẹẹ da ijọba ọhun pada fawọn alagbada. Latigba naa si ni awọn oloṣelu yii si ti n mura silẹ, wọn n reti ọjọ ti wọn yoo fọn fere, ti wọn yoo tun bẹrẹ ere ije wọn.

Nitori bẹẹ, wọn ko fẹ ki awọn ti wọn ki i ṣe ara awọn dara pọ mọ awọn, awọn ti wọn jẹ ara wọn nikan ni wọn fẹẹ maa ba ara wọn ṣe. Ọrọ naa gbona kaakiri ilẹ Yoruba, ṣugbọn ipo pataki ti Alaafin di mu ninu ọrọ awọn Yoruba yii jẹ ki nnkan le niluu Ọyọ, awọn ẹgbẹ oṣelu Ọlọpẹ ko fẹ ki Adeyẹmi jọba, awọn Parapọ ati NCNC  ko si fẹ ẹlomi-in loye ju Adeyẹmi lọ. Ohun to jẹ ki ọrọ naa le lẹyin ti Adeyẹmi ti jọba ree, ti awọn mi-in si kọ lati gba a bii Alaafin tawọn, wọn ni Alaafin awọn Parapọ ni, wọn ti gbagbe pe ijọba ologun lo ṣe ofin, ti wọn si fagi le ọrọ ẹjọ-pipe, lẹyin ti wọn ti fi ọdun meji aabọ ṣe ẹjọ loriṣiiriṣii, ti ọrọ naa ko ja sibi kan. Ibinu yii wa nilẹ, ko si tan ninu awọn alatako Lamidi Adeyẹmi, wọn n reti iyanu kan ti yoo tun jẹ ki ija naa bẹrẹ, ti wọn yoo si fi le le Adeyẹmi kuro nipo ọba.

Iru ọgbọn wo leeyan yoo da si iru ohun to wa nilẹ yii o. Adeyẹmi Alaafin sare pe awọn agbaagba ti wọn le da sọrọ naa jọ, ohun ti wọn si jọ fi ẹnu ko le lori ni pe ki awọn tilẹ kọkọ yanju ija to wa ni mọṣalaṣi na. Wọn ni nigba to jẹ ọpọ awọn eeyan yii, Musulumi lo pọ ju ninu wọn, bi ija ba ti le pari ni mọṣalaaṣi , ti awọn janmọ-ọn n kirun papọ, ti wọn n lọ si Yidi kan naa, yoo rọrun lati ba awọn oloṣelu to n lọ si awọn mọṣalaaṣi yii sọrọ. Bi nnkan ṣe wa nigba naa ni pe awọn oloṣelu Dẹmọ ati NCNC n lọ si mọṣalaaṣi kan ni, bẹẹ ni awọn ti ẹgbẹ Ọlọpẹ, n lọ si mọṣalaaṣi mi-in, kaluku n kirun ẹ lọtọọtọ ni. Ipade akọkọ ti Alaafin Adeyẹmi pe lori oye yii ko ṣiṣẹ rara, awọn to yẹ ki wọn wa ko wa, wọn ti gbin oro ara wọn sinu. Sibẹ naa, ọba yii tun gbiyanju, ṣugbọn nibi kọọ naa ni, ko jọ pe ija awọn ara mọṣalaaṣi yii yoo pari, nitori awọn oloṣelu ti wọnu wọn ni mọṣalaaṣi naa!

Ohun ti Alaafin waa ṣe ni pe o ni afi ki awọn maa woye ọrọ yii o, ki awọn si maa ṣe iṣẹ naa labẹlẹ, ki awọn ti ba gbogbo ọmọ lẹyin awọn lemọọmu yii sọrọ, pe eyi to ba dagba ju lọ ninu awọn lemọọmu yii, lọjọ to ba ti ku gbara, lọjọ naa ni eyi to ba wa laye ninu awọn lemọọmu mejeeji yoo di lemọọmu agba fun gbogbo Ọyọ, ti ko si ni i si ẹlomi-in ti yoo di ipo lemọọmu Ọyọ mu. Ko too digba ti iku yoo pa ẹnikankan ninu wọn ṣaa, Alaafin ti wa ọna pe awọn lemọọmu naa nikọọkan si aafin rẹ, to si ti ba wọn sọrọ pe ki wọn ma jẹ ki awọn oloṣelu da aarin wọn ru o, ki wọn ma jẹ ki oloṣelu gbe wọn ṣẹ Ọlọrun, ki wọn wa gbogbo ọna lati tun ilu Ọyọ ṣe ni. Ki wọn le mọ pe ọkan naa lawọn, ati pe oun ko ba ẹnikẹni ja, Alaafin Lamidi Adeyẹmi lọ si mọṣalaaṣi mejeeji lati kirun. O kirun ni takọkọ, o si tun lọọ kirun ni tikeji, ko si si ọjọ ti inu awọn ẹlẹsin yii dun ju ọjọ ti Alaafin de ọdọ wọn kirun lọ.

Nibi ti wọn ti n ṣe eyi ni ohun ti wọn ti sọ tẹlẹ ti ṣẹlẹ, ọkan ninu awọn lemọọmu naa ku lojiji. Kia ni wọn lọọ mu eyi to wa ni Parakoyi wa, wọn ni ko waa maa kirun ni mọṣalaaṣi nla keji, iyẹn mọṣalaaṣi Jimọ. Mọṣalaaṣi Paraoyi yii ni awọn ọmọ ẹgbẹ NCNC wa, kikida wọn lo kunbẹ fọfọ, wọn ki i si i fẹ ẹlomi-in laarin wọn. Nigba ti lemọọmu waa ku ninu mọṣalaaṣi Jimọ yii, wọn ni ki wọn ma fi mọṣalaaṣi ti Parakoyi ṣe Central mosque mọ, ṣugbọn ki lemọọmu wọn waa jẹ lemọọmu agba. Nibẹ ni wọn si pari ija naa si, nitori inu awọn ti mọṣalaaṣi Jimọ dun pe mọṣalaaṣi awọn naa lo pada di Central mosque, inu awọn ti Parakoyi naa si dun pe lemọọmu awọn lo pada di lemọọmu agba. Bi ija ti awọn musulumi ti pari ree, ti wọn si bẹrẹ ajọṣe tuntun. Wọn jọ n kirun, wọn si jọ n lọ si Yidi, ohun gbogbo si pada si bo ti yẹ ko ri.

Ṣugbọn kinni naa ko rọgbọ bẹẹ laarin awọn oloṣelu o, nitori ko i ti i ju oṣu kan lọ nigba ti wọn fi Lamidi Adeyẹmi jẹ Alaafin ti Ladepo Ọranlọla gbe ariwo nla kan jade, to ni awọn kan dẹ tọọgi soun o, ati pe diẹ lo ku ki wọn gba ẹmi oun. O ni niṣe ni awọn tọọgi naa deede ya lu oun bii ogiri alapa, ti wọn si mura lati gba ẹmi oun, ariwo ti wọn si n pa mọ oun lori ni pe ṣe oun loun laya ti oun n daamu ọba, oun loun n daamu Alaafin, ṣ’oun ko si ti i mọ pe o yẹ ki oun jawọ ninu ọrọ naa, oni loun maa lọ ba awọn baba baba oun lọrun. O ni ere buruku loun sa ti oun fi parẹ mọ wọn loju, nibi ti oun si sa wọ, oun farasoko sibẹ ni, oun ko si jade lati aarọ ṣulẹ, titi ti ilẹ ọjọ keji fi mọ, bẹẹ ni oun ko fi omi kan ẹnu oun bayii, nitori oun mọ pe awọn tọọgi naa n wa oun kiri. O ni bi oun ti raaye loun pariwo yii, ki gbogbo aye gba oun, ki wọn ma jẹ ki wọn fi tọọgi pa oun o.

Ewo lo tun ṣẹlẹ yii o. Ariwo tawọn eeyan n pa ree, nitori ohun to tun le fa iru eleyii ko yaayan lẹnu. Kia ni ọrọ naa ti di ohun ti awọn oloṣelu mejeeji fẹẹ maa woju ara wọn si, ti wọn si ti tun mura ija laarin ara wọn. Awọn ọmọ ẹgbẹ Ọlọpẹ ti bẹrẹ ariwo, wọn ni wọn fẹẹ pa Ladepo danu, nitori ko gba fun wọn ki wọn rẹ oun jẹ ni. Wọn ni bi wọn ba pa a, nnkan yoo ṣe, awọn lọọya ti wọn n lo naa si ti bẹrẹ si i sọrọ, wọn ni ohun ti awọn n wi lo ṣẹlẹ yii o, ẹmi onibaara awọn ko de rara, awọn si bẹ ijọba Western Region. Awọn tun kilọ fun wọn pe ti wọn o ba mojuto Ladepo Ọranlọla, ti wọn ba jẹ ki wọn pa a danu bẹẹ nitori pe ko ti i de ipo Alaafin, ọrun ijọba ni oku ọkunrin naa yoo wa o. Bẹẹ ni Ladepo paapaa funra ẹ naa n fọkoko kaakiri, to ni wọn n mura lati pa oun ni o, nitori wọn mọ pe oun ni gbogbo ilu yan bii Alaafin.

Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi ko sọrọ, koda ko gbin, ko sẹni ti yoo gbọ ọrọ kan lẹnu Alaafin. Ọrọ naa ti yatọ si igba ti wọn jọ n du kinni naa mọ ara wọn lọwọ, Alaafin ti wa lori oye, ọrọ ẹnu ẹ, aṣẹ ni. Ṣugbọn awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu NCNC sọrọ, wọn ni awọn mọ iru ohun ti Oranlọla n ṣe yii, wọn ni o kan fẹẹ maa pariwo lasan ki aye le maa gbọ orukọ ẹ ni, o ni ko i ti i gba pe reluwee ti ṣi, o si ti ja oun silẹ, ko si si ọna alumokọrọyi kan ti oun le gba ti oun yoo fi di Alaafin. Wọn ni ki lo de ti ko lọọ ba awọn ọlọpaa, bawo lo ṣe mọ pe ki i ṣe lara awọn eeyan oun ti awọn ti jọ n ditẹ lo yiju pada soun. Wọn ni wọn fẹẹ lo ọrọ naa lati ba orukọ Alaafin tuntun jẹ lasan ni, ṣugbọn eyi ko le ṣee ṣe fun wọn. Wọn ni Alaafin eleyii ti jokoo na, ko si kinni kan ti yoo le e lori aga ọba. Bẹẹ ni ọrọ di yẹbẹyẹbẹ, eeyan ko mọ boya loootọ lawọn tọọgi le Ladepo, eeyan ko si mọ boya ọrọ ti awọn alatako wọn sọ ootọ ni pe wọn fẹẹ ba orukọ ọba tuntun jẹ ni.

Ṣugbọn Alaafin ko jẹ ki ọrọ naa relẹ, o ni bi ina ko ba tan laṣọ ni, ẹjẹ ko ni i tan leeekanna, ohun to wa nilẹ naa lo wa nilẹ, afi ki awọn tete yaa mọ bi awọn yoo ṣe pana ẹ ko ma le ju bẹẹ lọ. N lo ba gbe igbimọ awọn agbaagba kan dide, o ni oun fa iṣẹ atunṣe Ọyọ le wọn lọwọ, gbogbo ibi ti ija ba wa, ki wọn pana ẹ kiakia, ki lu Ọyọ le roju, ko si dara lasiko toun.

Leave a Reply