Ijọba apapọ fẹẹ pese iṣẹ fun miliọnu marun-un eeyan

Oluyinka Soyemi

Ijọba apapọ ilẹ yii ti kede pe awọn yoo pese iṣẹ fun miliọnu marun-un eeyan gẹgẹ bii ileri tawọn ṣe tẹlẹ.

Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, lo kede ọrọ naa lasiko to n ṣepade pẹlu ileeṣẹ okoowo ipinlẹ Eko lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.

Ọṣinbajo ni eto iṣẹ agbẹ, ilegbee atawọn iṣẹ akanṣe mi-in yoo ran awọn ọdọ lọwọ lati ri iṣẹ nitori awọn nnkan ilẹ wa ti wọn yoo maa lo, eyi ti yoo din owo ti wọn yoo na lati pese awọn nnkan ti wọn fẹẹ ta ku, ki wọn le jere daadaa.

Bakan naa lo ni ile miliọnu marun-un nijọba n gbero lati fa ina to n lo oorun (Solar) si, eyi ti yoo ran awọn oniṣẹ-ọwọ lọwọ, paapaa awọn ileeṣẹ to n pese aṣọ to n ṣeto aabo lasiko arun Korona yii.

Leave a Reply