Ijọba apapọ fi kun owo-epo bẹntiroolu

Ijọba apapọ ilẹ Naijiria ti fi kun owo epo bẹntiroolu, eyi to gbera kuro ni naira mẹtalelọgọfa ataabọ (123.50) to wa tẹlẹ si naira mẹtalelogoje(N143) bayii.

Oni ti i ṣe ọjọ kin-in-ni, oṣu keje, ni eto tuntun naa bẹrẹ, ajọ to n ṣeto owo epo, Petroleum Products Pricing Regulatory Agency (PPPRA), lo si ṣe ikede ọhun.

Ẹka naa ṣalaye pe igbesẹ yii waye latari agbeyẹwo bi nnkan ṣe n lọ fawọn to n ṣòwò epo, idi niyi tawọn fi kede owo epo tuntun laarin ogoje naira (N140) si mẹtalelogoje naira(N143).

Tẹ o ba gbagbe, ẹka yii kede lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu karun-un, ọdun yii, pe awọn din owo epo ku si iye to wa laarin naira mọkanlelọgọfa aabọ (121.50) si mẹtalelọgọfa (123.50).

ALAROYE gbọ pe bi owo epo tun ṣe gbera lagbaaye lo fa igbesẹ tuntun yii.

 

Leave a Reply