Ijọba apapọ rọ kootu lati fagi le idajọ ile-ẹjọ to ni ki wọn fun Sunday Igboho lowo nla

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori bi ile-ẹjọ ṣe paṣe pe ki wọn san biliọnu lọna ogun Naira (₦20 bn) gẹgẹ bii owo itanran fun ajijagbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, fun bi awọn ọlọpaa abẹnu, DSS, ṣe lọọ paayan meji ninu ile ẹ, ti wọn si ba gbogbo dukia inu ile ọhun jẹ, ijọba apapọ orileede yii ti rọ ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun niluu Ibadan lati fagi le idajọ naa.

Ninu ẹjọ ti wọn pe ọhun, eyi to waye nile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun to wa laduugbo Ring Road, n’Ibadan, ni wọn ti bu ẹnu atẹ lu idajọ tile-ẹjọ giga da lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹsan-an, ọdun 2021, wọn ni idajọ ọhun ta ko awọn ofin orileede yii kan.

Lara ohun ti adajọ fi oju laifi wo ninu idajọ ẹ nigba naa lọhun-un ni bi wọn ṣe lọọ ṣigun ka Sunday Igboho mọle ẹ to wa laduugbo Soka, n’Ibadan, lọjọ kin-in-ni, oṣu Keje, ọdun 2021, ti wọn paayan meji nibẹ, ti wọn si ba ile tuntun, ile awoṣifila, ọhun jẹ pẹlu gbogbo dukia to wa ninu ẹ.

Lẹyin tori ti ko ajafẹtọọ Yoruba naa yọ lọwọ awọn iranṣẹ ijọba apapọ ti wọn fẹẹ pa a mọnu ile, nijọba orileede Benin mu un sọ satimọle lasiko to n rin irinajo lọ sorile-ede Germany. Ahamọ ọgba ẹwọn nibẹ lo si wa lati ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje, ọdun 2021.

Inu atimọle ọhun naa lo wa to ti pe ijọba lẹjọ, o ni ki wọn sanwo itanran fun bi wọn ṣe tẹ ẹtọ oun loju pẹlu bi wọn ṣe fipa wọ ibi gbogbo ninu ile oun, ati bi wọn ṣe pa meji ninu awọn eeyan oun pẹlu bi wọn ṣe bá gbogbo dukia oun pata jẹ.

Ẹẹdẹgbẹta biliọnu Naira (N500 bn) ni Sunday Igboho rọ ile-ẹjọ lati gba foun lọwọ ijọba Naijiria, ṣugbọn awọn aṣoju ijọba ta ko ibeere naa, wọn lẹjọ tọkunrin naa pe ko lẹsẹ nilẹ rara.

Ṣugbọn lẹyin atotonu awọn agbẹjọro olupẹjọ atawọn lọọya olujẹjọ l’Onidaajọ I. A. Akintọla da Sunday Igboho lare, o si pa ijọba apapọ laṣẹ lati san owo itanran biliọnu lọna ogun Naira lọjọ naa lọhun-un.

Idajọ atigba naa lawọn DSS ati Amofin-Agba Abubakar Malami ti i ṣe Minisita eto idajọ nilẹ yii ṣẹṣẹ pẹjọ ta ko nile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lorukọ ijọba apapọ yii, wọn lawọn ko tẹ ẹtọ

Sunday Igboho loju rara, nitori ofin orileede yii lodi si ki ẹnikẹni maa wa ọna lati jẹ ki Naijiria pin. Nigba to si ti jẹ pe ariwo ki wọn yọ ẹya Yoruba kuro lara Naijiria lolujẹjọ yii n pa, iya ti awọn fi jẹ ẹ ko ti i pọ ju nitori ẹni to ba pe ṣoṣo ni lati ri ṣoṣo ni.

Wọn waa rọ ile-ẹjọ lati fagi le idajọ to faini wọn lọdun to kọja ọhun, to si paṣẹ pe ki wọn da gbogbo dukia ẹ ti wọn ji ko ninu ile ẹ pada nitori idajọ to fẹẹ fiya jẹ awọn lọna aibofinmu lasan ni.

Leave a Reply