Ijọba apapọ fọwọ si i pe ki wọn fi Kyari ranṣẹ s’Amẹrika ti wọn ti n wa a

Ọrẹoluwa Adedeji

Ijọba apapọ ti fọwọ si i pe ki wọn fi igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa to wa nidii gbogbo awọn iwa ọdaran ati iṣẹlẹ idigunjale ati ijinigbe to ba lagbara nilẹ wa nni, Abba Kyari, ranṣẹ sawọn ọlọpaa ilu oyinbo ti wọn ti n beere fun un pe ko waa jẹjọ lori awọn ẹsun jibiti ti wọn fi kan an lori owo ti ọkan ninu awọn ọmọ ilẹ wa, Abass Rahmon ti gbogbo eeyan mọ si Hushpuppy atawọn mẹrin mi-in lu jibiti rẹ, ($1.1m) ti wọn si ni ọga ọlọpaa yii mọ nipa rẹ.

Minisita feto idajọ nilẹ wa, Abubakar Malami, lo gbe iwe ẹsun naa lọ siwaju adajọ agba nile-ẹjọ giga to wa niluu Abuja, pẹlu iwe to ni nọmba FHC/AB/CS/ABJ/CS/249/2022, labẹ ẹsun pipe eeyan pada tabi fifi ranṣẹ.

Malami ni igbesẹ lati beere labẹ ofin fun fifi Kyari ranṣẹ waye nitori bi awọn ara ilẹ Amẹrika ṣe beere fun un lati waa sọ ohun to mọ nipa awọn ẹsun mẹta kan ti wọn fi kan an lasiko iwadii wọn.

Ninu iwe ti Malami gbe lọ siwaju ile-ẹjọ lati fara mọ bi wọn ṣe ni ki ọga ọlọpaa naa wa silẹ Amẹrika lati waa wi tenu rẹ lo ti sọ pe inu oun dun fun awọn ofin to rọ mọ lilọ Kyari naa nitori pe ki i ṣe pe wọn fẹẹ fiya jẹ ẹ nitori ẹya to ti wa, tabi ẹsin to n sin, tabi nitori pe o jẹ ọmọ orileede Naijiria, ṣugbọn lọna to tọ ni wọn fẹẹ fi wadii rẹ, leyii to ba ofin mu pẹlu.

O fi kun un pe tẹlẹtẹlẹ, yoo jẹ ohun ti ko tọna, ti yoo si jọ bii ifiya jẹ ni tabi ifọwọ ọla gba ni loju lati kan taari rẹ sijọba ilẹ Amẹrika bẹẹ beeyan ba kọkọ wo gbogbo ohun to yi bi wọn ṣe pe e ka.

O ni ṣugbọn ni bayii, o tẹ oun lọrun pe wọn ti fẹsun kan ọga ọlọpaa naa lori awọn ẹsun ti wọn n tori ẹ wa a l’Amẹrika.

Malami fi kun un pe ko si ẹjọ iwa ọdaran to jẹ mọ eyi ti wọn fẹẹ tori ẹ mu un lọ si Amẹrika yii to n jẹ ni Naijiria lọwọlọwọ.

Tẹ o ba gbagbe, ninu oṣu kẹrin, ọdun yii, ni ile-ẹjọ kan, Disirict Court for the Central District of California nilẹ Amẹrikan fẹsun kan ọga ọlọpaa ilẹ wa yii pe o ṣe agbodegba awọn owo kan, o lu jibiti ati arọndarọnda owo. Wọn lọmọkunrin kan ti wọn n pe ni Rahmon Abass Ọlọrunwa to jẹ ọmọ Naijiria ni ọga ọlọpaa yii lẹdi apo pọ mọ. Eyi lo mu ki ijọba ilẹ Amẹrika ni ki wọn yọnda ọkunrin naa ko waa jẹjọ awọn ẹsun ti wọn ka si i lẹsẹ lasiko iwadii wọn ọhun.

Latigba naa ni ariwo ti n lọ loriṣiiriṣii lori boya wọn yoo fi i ranṣẹ tabi wọn ko ni i fi i ransẹ. Nigba to ya nileeṣẹ ọlọpaa gbe igbimọ kan kalẹ lati wadii rẹ. Igbimọ ti wọn gbe kalẹ naa ni wọn ni wọn ko ṣiṣẹ wọn daadaa ti wọn fi tun gbe igbimọ mi-in kalẹ, tawọn yẹn si ni ki wọn ja ipo rẹ wa silẹ gẹgẹ bii ijiya ohun to ṣe. Eyi ni awọn ọmọ Naijiria n sọ lọwọ pe ijiya naa ti kere ju ti ileesẹ to n gbogun ti tita ati mimu oogun oloro nilẹ wa (NDLEA), fi tun jade pe ọkunrin naa lẹjọ i jẹ. Wọn lo n ṣagbodegba fawọn to n ko oogun oloro wọ ilẹ wa.

Ọdọ awọn ajọ yii lo si wa titi di ba a ṣe n sọ yii. Bi igbẹjọ naa ba ti waye ti wọn si yanju gbogbo ọrọ, a jẹ pe Kyari yoo fẹsẹ kan yọju si wọn l’Amẹrika.

Leave a Reply