Ijọba bẹrẹ atunṣe ileeṣẹ omi-ẹrọ l’Ọyun/Ọffa, nipinlẹ Kwara

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Lati fopin si iya to maa n jẹ araalu lasiko ọgbẹlẹ, ijọba ipinlẹ Kwara ti bẹrẹ atunṣe awọn ẹrọ ipese omi nijọba ibilẹ Ọyun ati Ọffa, eyi to ti dẹnukọlẹ tipẹ.

Igbesẹ yii waye latari akitiyan ijọba Gomina Abdulrazaq Abdulrahman lati pese omi to mọ gaara to ṣee mu ati bu’wẹ fun araalu.

Ṣaaju nijọba ti ṣe atunṣe awọn ibudo ipese omi ẹrọ kaakiri ipinlẹ Kwara, eyi to n pese omi fun araalu nijọba ibilẹ Ọyun ati Ọffa jẹ ọkan lara awọn ibudo to nilo atunṣe.

Lara igbesẹ tijọba tun ti gbe ni ṣiṣe atunṣe awọn tanki omi ‘Up Lawal’ tijọba ana pada yi si ‘Up Kwara’ eyi ti wọn ti pati, to wa kaakiri igboro ilu Ilọrin fun lilo.

ALAROYE ṣakiyesi pe awọn onimọ-ẹrọ ṣi wa lẹnu iṣẹ lasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ.

 

caption: Awọn ẹnginia to n ṣiṣẹ nibudo ipese omi fun ijọba Ọyun ati Ọffa

 

Leave a Reply