Ijọba Buhari ti da Ọga yunifasiti Eko pada sipo  ẹ

Aderounmu Kazeem
Ijọba apapọ orilẹ ede yii ti tu igbimọ to n dari akoso Yunifasiti Eko, UNILAG, ka, bẹẹ lo paṣẹ ki Ọjọgbọn Oluwatoyin Ogundipẹ pada sipo olori ileewe naa, nitori ọna ti wọn gba yọ ọ ko tọna rara.
Oni, Wẹsidee, Ọjọruu, ni igbesẹ ọhun waye, wọn ni ki Ogundipẹ maa ba iṣẹ ẹ lọ.
Ijọba apapọ sọ pe oun gbe igbesẹ lati da ọga ileewe ọhun pada sẹnu iṣẹ ẹ latara abajade iwadii igbimọ to ṣabẹwo sí Yunifasiti ọhun, to si fidi ẹ mulẹ wi pe ọna ti wọn gba gbaṣẹ lọwọ Ọjọgbọn yii ku diẹ kaato.
Ọgbẹni Ben-Bem Goong, agbẹnusọ fun ileeṣẹ to n rí si eto ẹkọ, sọ pe igbimọ to ṣabẹwo ọhun ri i pe niṣe ni wọn yọ Ogundipẹ lọna ti ko tọ, ti wọn sì fi Ọjọgbọn Ṣoyọmbọ rọpo ẹ lai tẹle Ilana to yẹ.
Bakan naa ni igbimọ yii ke sí ijọba apapọ ko ṣe agbekalẹ igbimọ ti yóò lọ sileewe ọhun lati ṣewadii ẹsun tí wọn fi kan Ogundipẹ atawọn yooku ẹ.
Ninu ọrọ ti igbimọ ti ijọba apapọ gbe kalẹ fi sita lo ti sọ pe Aarẹ Muhammadu Buhari ati igbimọ to ṣabẹwo si ileewe UNILAG ti fọwọ si abajade awọn ọmọ igbimọ ọhun, bẹẹ lo foju han wí pé wọn kò fun ọga ileewe UNILAG yii lanfaani lati sọ tẹnu ẹ. Fún ìdí èyí, ki wọn da a pada sipo rẹ ko máa bá iṣẹ ẹ lọ.
Ni bayii, wọn ti tu igbimọ ti Dokita. B. O. Babalakin jẹ alága ẹ ka, bakan naa ni Aarẹ Muhammadu Buhari sọ pe oun lero pe igbesẹ yii yóò dá alaafia pada sinu ọgbà Yunifasiti ọhun.

Leave a Reply