Ijọba Buhari ti kuna, bii eyi ti wọn fi gegun-un lo ri- Tunde Bakare

Adefunke Adebiyi

Ọrọ ayajọ inu Bibeli, iru eyi ti Daniẹli fi ṣalaye ọrọ fun ọba Belshazzar to beere awọn alaye kan lọwọ ẹ nipa ijọba rẹ, ni Pasitọ Tunde Bakare, ti ijọ Citadel Global Community Church, fi ṣatupalẹ ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari, nigba to n sọrọ nipa ipo ti Naijiria wa bayii fawọn ọmọ ijọ, lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ ọdun Ajinde Jesu Oluwa.

Pasitọ Bakare sọ pe a ti fa iwe ijọba yii ya, ọjọ rẹ lori aleefa ku perete pẹlu bo ṣe jẹ pe ko kunju oṣuwọn lawọn ibi to yẹ gbogbo ti wọn ti gbe e sori iwọn.

Lawẹlawẹ ni Pasitọ Bakare ṣi alaye rẹ naa, o sọrọ nipa awọn nnkan ti ijọba Buhari rawọ le ni saa keji yii, o ni aṣiṣe gbaa ni.

‘Next Level agenda’ iyẹn ipele to kan ti wọn rawọ le, ti wọn tun gbe e kuro ni ẹka mẹta to wa ni 2015, ti wọn sọ ọ di mẹsan-an, ṣakoba fun wọn pupọ, o si sọ wọn dẹni to fi ẹtẹ silẹ to n pa lapalapa.

Pasitọ ṣalaye pe Aarẹ gbagbe awọn alatako rẹ, o gbagbe ohun to kan, o nawọ sohun tọwọ rẹ ko to, ohun to si fa wahala niyẹn.

O loun ko sọ pe koko ti wọn gun le ni Next Level ko ṣe pataki o, ṣugbọn ko sẹni ti ko mọ pe omi pọ ju ọka lọ.

O sọ nipa eto aabo to bajẹ debii pe nigba ti Aarẹ Buhari sọ pe ijọba oun ti kapa Boko Haraamu lawọn iyẹn n doju kọ odidi abule, ti wọn n pa wọn run tan. Igba naa lo di pe ṣọja n sa loju ogun nigba ti apa wọn ko ka Boko Haram. O lọdun keje ree ti wọn ji awọn akẹkọọ gbe ni Dapchi, to jẹ wọn o ti i ri wọn gba kalẹ tan, Leah Sharibu naa wa nibẹ, ti wọn lo ti bimọ keji fawọn Boko Haram gan-an.

Bakare ni ọrọ-aje naa bajẹ kọja aala, iwa ibajẹ ti Buhari loun yoo gbogun ti paapaa gbokun si i ni. Pasitọ Bakare sọ pe awọn eeyan nla ni Naijiria naa kuku jẹrii si i pe nnkan ti bajẹ ni Naijiria yii, o ni Emir ilu Daura ti Buhari ti wa, Alaaji Faruk Umar, wo ohun to n ṣẹlẹ titi, o si sọ pe ohun ti Naijiiria n la kọja lasiko yii buru ju ogun abẹle lọ.

Sultan ilu Sokoto naa sọ tiẹ, iyẹn Alaaji Muhammadu Sa’ad, o ni ibi to buru ju lati gbe lorilẹ-ede bayii ni ilẹ Hausa, nitori niṣe lawọn ajinigbe n kiri abule kiri, ti wọn n lọ sawọn ọja tibọn-tibọn AK47 lọwọ, ti ko si sẹnikan ti yoo bi wọn bi wọn ba n jiiyan gbe, ti wọn n pa aye run lai ṣẹ wọn lẹṣẹ kan.

Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi naa ti sọrọ nipa biluu ṣe ri, lorukọ awọn ọba ilẹ Yoruba lo si ti sọrọ ọhun bi pasitọ ṣe sọ.

Ohun ti gbogbo wọn n sọ naa ni pe gadagba lo han nibi ti wọn kọ ọ si, pe ijọba yii ti kuna, bii eyi ti wọn fi gegun lo ri.

Leave a Reply