Ijọba Buhari yari mọ Rotimi Akeredolu lọwọ, o ni ko gbọdọ le awọn Fulani darandaran l’Ondo

Dada Ajikanje

 

Aarẹ Muhammadu Buhari ti bu ẹnu atẹ lu bi Gomina Rotimi Akeredolu ṣe paṣẹ fawọn Hausa darandaran ki wọn ko awọn maaluu wọn kuro ninu awọn igbo ti ijọba ya sọtọ nipinlẹ Ondo.

Ninu ọrọ ti Garba Shehu, Oluranlọwọ Aarẹ Buhari, sọ lọjọ lṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lo ti sọ pe Buhari ko fara mọ ọrọ ti gomina ọhun sọ pe awọn Fulani ti wọn n da maaluu kaakiri ipinlẹ Ondo gbodọ fi ipinlẹ ohun silẹ.

Garba Shehu ti sọ pe igbesẹ Gomina Rotimi Akeredolu ta ko ofin orilẹ-ede yii, nitori ko bojumu ko le awọn darandaran kuro nipinlẹ naa lori ọrọ eto aabo lai tẹle ofin Naijiria.

O fi kun un pe gẹgẹ bi amofin agba ti gomina ọhun i ṣe, ko ni i bojumu to ba jẹ pe oun lo waa hu iru iwa bẹẹ nipa lile gbogbo awọn eeyan ti wọn ti lo gbogbo ọjọ aye wọn nipinlẹ naa nitori ti awọn kan ninu wọn n hu iwa janduku.

O ni ko bojumu lati maa lọ ọrọ aabo mọ ẹya kan, tabi ede tawọn kan n sọ, abi ẹsin ti wọn n ṣe mọ ọrọ aabo ti ko ṣe deede nipinlẹ ọhun.

Oluranlọwọ Aarẹ yii sọ pe ohun to fa ọrọ yii ko ju aigbọra-ẹni-ye lọ. O lohun to ṣe pataki ni ki asọyepọ tubọ tẹ siwaju laarin aṣaaju awọn darandaran yii ati ijọba, ki igbọra-ẹni-ye le tubọ fẹsẹ rinlẹ daadaa dipo bo ṣe ni ki wọn fi ipinlẹ ọhun silẹ, eyi to ṣee ṣe ko di alaafia ilu lọwọ.

O fi kun un pe ijọba apapọ ko ni i faaye gba ijinigbe atawọn iwa janduku mi-in lọwọ ẹnikẹni, ati pe ki i ṣe ohun to dara bi awọn eeyan kan lorilẹ-ede yii ṣe n tọka iwa janduku, ijinigbe atawọn iwa ọdaran mi-in gẹgẹ bii ohun ti awọn ẹya kan fẹran lati maa ṣe. O ni eyi ko dun mọ ijọba apapọ ninu rara, ati pe asiko niyi lati yẹra fun iru igbagbọ bẹẹ pe awọn Fulani darandaran ni wọn wa nidii idaluru loriṣiiriṣii.

O ni ohun to jẹ ijọba Buhari logun ni bi ọmọ Naijiria yoo ṣe le gbe ibi yoowu to ba wu wọn nibikibi ni Naijiria.

Garba sọ pe eyi lo mu Buhari ta ko awọn IPOB ti wọn lawọn n ja fun Biafra, nigba ti wọn sọ pe ki awọn Hausa kuro lagbegbe wọn. O ni bẹẹ naa lo tun ta ko awọn ijọ Musulumi kan ti wọn sọ pe ki Bisọọbu Mathew Kukah kuro ni Sokoto, iyẹn laipẹ yii.

Agbẹnusọ fun Buhari yii ti waa sọ pe ijọba apapọ ti loun ko ni i faaye gba iru iwa idunkooko mọ ni bẹẹ, ati pe ohun to ṣe pataki bayii fun gbogbo gomina ipinlẹ bii mẹrindinlogoji to wa lorile-ẹde yii ni bi wọn yoo ṣe mu eto aabo wọn ko le dan-in-dan-in ki aala si wa laarin awọn janduku adaluru ati awọn ọmọ orilẹ-ede yii ti wọn ko ni ohunkohun ṣe pẹlu iwa ọdaran.

Leave a Reply