Ijọba Buhari yari, o loun ko ni i din owo ọkọ reluwee lati Eko si Ibadan ku

Jide Alabi

Bo tilẹ jẹ pe ariwo ti araalu n pa lori iye ti wọn yoo maa san lati wọ ọkọ oju irin lati Eko lọ si Ibadan ti wọn ju, sibẹ, ijọba apapọ ti sọ pe oun ko le dinwo ọhun ku rara.

Lasiko ti ọga agba fun ileeṣẹ reluwee, Fidet Okhiria, n ba awọn oniroyin sọrọ lori aṣeyọri ti ileeṣẹ naa ti n ṣe bayii lori bi awọn eeyan ṣe n jade lati wọ ọkọ naa lo fidi ọrọ ọhun mulẹ.

Okhiria sọ pe bo tilẹ jẹ pe eeyan kan ṣoṣo pere lo wọ reluwee ọhun lọjọ keje, oṣu kejila, nigba to bẹrẹ iṣẹ lati maa na Eko si Ibadan, ti eeyan mẹjọ si wọ ọ pada si Eko lọjọ naa, sibẹ ayipada rere ti n ṣẹlẹ bayii.

O ni eeyan mẹtadinlaaadọwa (187) ni reluwee ọhun n ri gbe bayii lọ si Ibadan, ti yoo si tun ri ero rẹpẹtẹ ko pada si Eko.

O ni eyi fi han pe aṣeyọri nla ti n ba eto irinna ọhun, yatọ si ariwo ti awọn araalu kọkọ mu bọ ẹnu tẹlẹ pe owo ti wọn fẹẹ maa gbero ti wọn ju.

Tẹ o ba gbagbe, nigba ti ọkọ oju irin tuntun yii bẹrẹ iṣẹ, ẹgbẹrun meji abọ, iyẹn (N2,500) ni wọn sọ pe wọn yoo maa wọ ipele to kere ju, nigba ti eyi to tẹle e jẹ ẹgbẹrun marun-un naira, ti eyi ti ipo ẹ ga ju si jẹ egbẹrun mẹfa naira pẹlu.

Okhiria sọ pe, “Ọna kan pataki ti a le gba fi ṣaṣeyọri ni ki araalu ba wa fara mọ iye ti a ni ki wọn maa wọ ọ, nitori a gb̀ọdọ maa sanwo fawọn oṣiṣẹ ti wọn maa n fi ara wọn silẹ lati ṣiṣẹ kun iṣe wọn yatọ si akoko ti a jọ ni adehun pẹlu wọn. Fun idi eyi, ijọba ko ṣetan lati ṣadinku owo ọhun, iye ta a pe e naa lawọn eeyan yoo maa wọ ọ, a si dupẹ pe awọn eeyan ti n wọ ọ daadaa bayii.”

Leave a Reply