Ijọba Buhari yii lo n sọ awọn ọmọ Naijiria dọta ara wọn, Ọbasanjọ lo sọ bẹẹ

“Lọjọ ti mo ti gbọnju, emi o ri igba kankan ni orilẹ-ede wa yii ti awọn  Ọmọ Naijiria pin si yẹlẹyẹlẹ bayii, ti awọn ẹya gbogbo n di ọta ara wọn. Asiko ijọba ti a ni yii ni iru ẹ n ṣẹlẹ, ohun ti gbogbo wa si gbọdọ moju to ko too di ohun ti yoo fọ Naijiria patapata ni!” Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ lo n ṣe bayii sọrọ nibi ipade awọn agbaagba orilẹ-ede yii kan niluu Abuja, ni Ọjobọ,  Tọsidee, ana yii.

Ẹni to ti fi igba kan jẹ olori ilẹ wa yii sọ pe gbogbo ikunsinu ati ede-aiyede laarin ẹya gbogbo ni Naijiria to ti n di ohun igbagbe ni bii ọdun mẹwaa sẹyin, gbogob ẹ ni ijọba yii ti fi àìlákiyèsí ati eto wúruwùru ji dide pada, ti kinni naa si n le ju bo ti wa tẹlẹ lọ. “Nidii eyi”, gẹgẹ bi Ọbasanjọ ti wi, “eto ọrọ aje wa ko dara, eto aabo ilẹ wa ko sunwọn, ohun amayedẹrun gbogbo n bajẹ, debii pe Naijiria ti fẹẹ di ọkan ninu awọn orilẹ-ede to ja kulẹ lagbaaye, ati orilẹ-ede ti ọrọ wọn da bii ti afapẹ̀rẹ̀-pọnmi, awọn aláṣedànù lasan!”

Nibi ipade Abuja ti Ọbasanjọ ti n sọro yii, oju pe ẹsẹ pele ni, nitori awọn aṣoju ẹgbẹ Afẹnifẹre wa nibẹ, bẹe lawọn aṣaaju Ijaw lati Naija-Dẹlita, bẹẹ lawọn ẹgbẹ agbaagba ilẹ Ibo ti wọn n pe ni Ohaneze, awọn ẹgbẹ aagbaaga ilẹ Hausa, ati awọn aṣoju lati aarin-gbungbun Naijiria (Middle Belt). Nibi yii ni Ọbasanjọ ti sọ pe eyi ti ijọba Buhari da silẹ ninu ọrọ yii ni i jẹ oun, nitori lati igba ti wọn ti de yii, gbogbo awọn ohun ti wọn ti fi ọgbọn lẹ pọ tẹlẹ lawọn bẹrẹ si i tuka: ti wọn fẹẹ mọ ohun to n sọrọ ninu redio; bẹẹ ẹni to ba fẹẹ mọ ohun to n sọro ninu redio yoo ba iṣẹ oyinbo jẹ ni.

Ọbasanjo ni ohun to fa a ti gbogbo ẹya fi n pe awọn fẹe ṣe tawọn lọtọ, awọn ko ṣe Naijiria mọ, bayii ni iwa ailododo, aiṣe-deede ati iwa ẹlẹyamẹya laarin awọn ti wọn n ṣejọba, pe ti Naijiria ba ri bo ti yẹ ko ri ni, ko ni i si ẹya kan ti yoo sọ  pe oun  n lọ sibi kan. Idi ni pe ko si ibi ti a le gba sa funra wa, nitori koda ki a ma jọ jẹ ọmọ orilẹ-ede kan naa mọ, aladuugbo ara wa ni a oo ṣi maa jẹ titi aye, ẹni kan ko saa ni i fi adugbo tirẹ silẹ fẹni kan. O ni ki ijọba Buhari tete yi nnkan pada, ki wọn ma jẹ ki Naijiria fọ mọ wọn lori o.

4 thoughts on “Ijọba Buhari yii lo n sọ awọn ọmọ Naijiria dọta ara wọn, Ọbasanjọ lo sọ bẹẹ

Leave a Reply