Ijọba da ọwọ oṣu ọba Iṣaoye duro l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Nitori pe o fi ilu silẹ fun odidi ọdun mẹta gbako, to si tun kọ lati ṣe ojuṣe rẹ nidii oriṣa ilu rẹ, ijọba ipinle Ekiti ti paṣẹ pe oun ti da owo oṣu Ọba Gabriel Olajide, duro.

Kabiyesi yii to ti figba kan jẹ ọga ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, to si tun jẹ Ọbasaoye tilu Isaoye, nijọba ibilẹ Mọba, nipinlẹ Ekiti, ni wọn fẹsun kan pe o fi ilu naa silẹ fun odindi ọdun mẹta gbako, ti ko si ṣe ojuṣe rẹ gẹgẹ bii ọba.

Igbakeji gomina ipinlẹ Ekiti, Ọtunba Bisi Ẹgbẹyẹmi, lo paṣẹ naa lọjọ Ẹti, niluu Ado-Ekiti, ni kete to ṣepade alaafia kan pelu awọn oloye ati awọn ọmọ ilu Isaoye, eyi to waye nile ijọba ipinlẹ Ekiti.

Ṣe ṣaaju ni awọn ọmọ bibi ilu naa ti kọ lẹta ifẹhonu han kan si ijọba ipinlẹ naa, nibi ti wọn ti fẹsun kan ọba alaye naa pe niṣe lo sa kuro niluu, to si pa ojuṣe rẹ ti, pẹlu awọn ẹsun mi-in.

Ninu iwe kan ti Oludamọran si Igbakeji gomina, Ọgbẹni Ọdunayọ Ogunmọla, fi lede lori ọrọ yii, o ni ipade naa waye latari olobo kan ti awọn ọlọpaa bonkẹlẹ (DSS) ta ijọba Ekiti pe o ṣee ṣe ki wahala ati rogbodiyan bẹ silẹ laarin ọba naa ati awọn ara ilu rẹ.

Ninu lẹta naa ni wọn tun ti fẹsun kan Kabiyesi naa pe ko bọwọ fun aṣa ibilẹ ilu naa, wọn leyii wa lara ohun to fẹẹ fa rogbodiyan ọhun.

Ṣugbọn nigba to n fesi si ọrọ naa, Ọba Olajide ni loootọ loun fi ilu naa silẹ fun bii ọdun mẹta sẹyin, ko si si ohun to le yi ero oun pada lori eyi.

O ni awọn ara ilu oun ni wọn ko gba oun laaye lati wọlu naa koun le ṣe ojuṣe oun gẹgẹ bii ọba.

Igbakeji gomina yii lo paṣẹ lọgan pe ki ijọba ibilẹ Mọba ti ilu Iṣaoye wa labẹ rẹ da owo-oṣu Kabiyesi naa duro, o si tun paṣẹ pe ki awọn ara ilu naa bẹrẹ igbesẹ lati yọ ọba Ọlajide nipo lọgan.

O ni igbese lati yọ ọba naa nipo ti wa ni iwaju igbimọ awọn lọbalọba ipinlẹ naa.

Gẹgẹ bii ọrọ Igbakeji gomina naa, o ni “Awọn ara ilu fi ẹ jẹ ọba, ṣugbọn o kọ lati duro sinu ilu naa lati ṣe ojuṣe rẹ gẹgẹ bii ọba, lẹyin eyi, nitori pe o jẹ ọga ninu iṣẹ ọlọpaa, o bẹrẹ si i lo ipo rẹ lati fiya jẹ awọn ara ilu to o jọba le lori.

“Mo ti sọ fun ẹ lati ọdun mẹta sẹyin pe to ba jẹ ọba lo fẹ tabi iṣẹ ọlọpaa rẹ lo fẹran ju, fọwọ mu ọkan, o si kọ lati ṣe ojuṣe rẹ nidii oriṣa ilu naa, ko sigba ti wahala ati rogbodiyan ko ni i maa waye laarin iwọ ati awọn ara ilu.

O wa ni ilu odikeji,  o n ko awọn janduku ati awọn ọlọpaa waa mu awọn ara ilu to o jọba le lori, ẹni to fẹẹ jẹ oye “Ẹyẹbasa” ti yoo maa bọ oriṣa ilu naa, o ko jẹ ko jẹ ẹ lẹyin tijọba ti fọwọ si oye naa lati nnkan bii ọdun meji sẹyin.

 

Leave a Reply