Ijọba Dapọ Abiọdun fẹẹ pese BRT fawọn eeyan ipinlẹ Ogun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Gẹgẹ bi ọkọ bọginni akero ti wọn n pe ni BRT ṣe n ṣiṣẹ nipinlẹ Eko, to si n din iṣoro ọkọ wiwọ ku, ijọba ipinlẹ Ogun naa ti ni oun yoo bẹrẹ eto lori bi ọkọ BRT yoo ṣe maa ṣiṣẹ nipinlẹ yii pẹlu.

Kọmiṣanna fun igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Ogun, Gbenga Dairo, lo sọ eyi di mimọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹjọ, l’Abẹokuta.

Dairo ṣalaye pe  ọpọ eeyan lo n gbe nipinlẹ Ogun to jẹ pe Eko ni wọn ti n ṣiṣẹ, eyi lo ni o maa n fa a to jẹ pe laaarọ, ero rẹpẹtẹ lo n jade lati Ogun lọ si Eko, to ba tun di nirọlẹ, wọn yoo tun dari pada wa sile labẹ sun-kẹrẹ fa-kẹre.

Lati ran iru awọn wọnyi lọwọ ni eto BRT yii yoo ṣe gbera sọ gẹgẹ bo ṣe wi.

Awọn agbegbe bii Ọta si Mowe-Ibafo ni eto yii yoo kan, bẹẹ ni eto kan naa yoo tun wa fawọn eeyan to n ti inu adugbo jade si Mowe lọ si Eko, ‘Park and Ride Service ni kọmiṣanna pe eyi.

Awọn adugbo kan wa to ṣoroo mọ boya Eko tilẹ ni wọn tabi Ogun, nitori wọn ti wọnu ara wọn gẹgẹ bi Dairo ṣe wi. Iru awọn agbegbe bii eyi yoo ni anfaani lati wọ ọkọ BRT lati agbegbe wọn, yala Ogun, tabi Eko.

Kọmiṣanna waa rọ ijọba ipinlẹ Eko pe ki wọn nawọ oore BRT ti wọn ṣẹṣẹ fi lọlẹ lati Oṣodi si Abule-Ẹgba, si awọn, ki wọn jẹ ko de agbegbe Ọta, ki iṣoro ọkọ wiwọ tun le ṣẹ pẹrẹ diẹ nibẹ yẹn si i.

 

Leave a Reply