Ijọba dawọ yiyan ọba tuntun duro niluu Awo-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii nijọba ipinlẹ Ekiti paṣẹ pe ki awọn afọbajẹ ati oloye ilu Awo-Ekiti, nijọba ibilẹ Irẹpọdun/Ifẹlodun, dawọ fifi ọba miiran jẹ niluu naa duro titi ti ẹjọ to wa nile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun yoo fi pari.

Igbakeji Gomina ipinlẹ naa, Oloye Bisi Ẹgbẹyẹmi, lo  paṣẹ naa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, nigba to ṣe ipade pẹlu awọn oloye ati afọbajẹ ilu naa. O ni igbesẹ ijọba lati da fifi ọba miiran jẹ niluu naa duro waye lẹyin eto aabo ti awọn ẹṣọ alaabo sọ pe o ku diẹ ni ilu naa.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹta,  ọdun 2021, nile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Ekiti yọ ọba Abdulazeez Ọlalẹyẹ nipo, lori ẹsun ti awọn ara ilu rẹ fi kan an pe ko kunju oṣuwọn.

Lọgan ni ọba alaye yii fori le ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun to si pẹjọ ta ko iyọnipo rẹ. Ijọba to kuro lori aleefa nipinlẹ Ekiti lo fi Ọba Ọlalẹyẹ sori ipo lọdun 2017.

Igbakeji gomina kilọ fun awọn afọbajẹ ninu iwe kan ti Akọwe iroyin rẹ, Ogbeni Odunayo Ogunmola, fi sọwọ sawọn oniroyin pe ki wọn gba alaafia laaye, ati pe ki wọn jawọ ninu igbesẹ to le fa rogbodiyan niluu naa, ki wọn jẹ ki ẹjọ to wa nile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun pari ki wọn too ṣe ohunkohun.

Ẹgbẹyẹmi sọ pe wọn ta ijọba lolobo pe igbesẹ ti n lọ lati fi ọba Alawo miiran jẹ nigba ti ẹjọ ṣi wa nile-ẹjọ, o si jẹ ohun to lodi sofin.

Ninu ipade naa, awọn oloye ilu ọhun mẹta ti wọn fi ẹsun kan pe o n gbe igbesẹ lati fi ọba tuntun jẹ ṣalaye pe awọn ko si nidii ọrọ naa. Ṣugbọn Igbakeji gomina yii ṣalaye pe niwọn igba ti ọba ti ile-ẹjọ yọ nipo yii ba ti pe ẹjọ ta ko idajọ naa, awọn afọbajẹ ni lati duro di igba ti ile-ẹjọ yoo da ẹjọ yii.

O ṣalaye pe ijọba ipinlẹ naa ni ko ni i kawọ gbera lati maa wo igbesẹ to tẹ ofin loju tabi to le da omi alaafia ilu Awo-Ekiti ru. O kilọ pe ọwọ ofin yoo tẹ ẹnikẹni to ba fẹẹ da omi alaafia ilu ọhun ru lori ọrọ ipo ọba niluu naa.

Gẹgẹ bii ọrọ rẹ, “Ẹ ni lati ni suuru titi digba ti ile-ẹjọ yoo pari igbẹjọ naa, ki ẹ too gbe igbesẹ kankan, afobajẹ to ba ṣe eleyii fẹẹ tẹ ofin loju ni. Ki ẹnikẹni ma ṣe gbe igbesẹ to le fa wahala tabi to le da omi alaafia ru niluu rẹ tabi nipinlẹ Ekiti lapapọ.”

Leave a Reply