Ijọba Ekiti ṣawari awọn ayederu oṣiṣẹ to n gba miliọnu mọkandinlogun naira loṣooṣu

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ijọba ipinlẹ Ekiti ti ṣawari ayederu oṣiṣẹ ọọdunrun-le-mejilelọgọta (362) ti wọn n gba owooṣu to le ni miliọnu mọkandinlogun naira (N19.3m) lawọn ijọba ibilẹ loṣooṣu.

Awọn oṣiṣẹ naa la gbọ pe wọn ko si nibi iṣẹ to yẹ ki wọn maa ṣe, ṣugbọn ti wọn n gba owo oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ deede.

Eyi ni abajade igbimọ ti Gomina Kayọde Fayẹmi ṣagbekalẹ lati mọ awọn to jẹ ojulowo oṣiṣẹ lawọn ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa l’Ekiti. Nibẹrẹ ọdun yii ni gomina ṣagbekalẹ igbimọ ẹlẹni mọkanla kan ati igbimọ alabẹ-ṣeleke ẹlẹni meje mi-in lati ṣewadii awọn oṣiṣẹ,  lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni wọn si gbe aabọ iwadii wọn fun un.

Ọkan ninu awọn alaga igbimọ mejeeji to tun jẹ Kọmiṣanna fọrọ ijọba ibilẹ, Ọjọgbọn Adio Afọlayan, ṣalaye pe ninu akọsilẹ awọn to n gbowo lawọn ijọba ibilẹ lawọn ti ṣawari awọn eeyan naa, awọn si ti ṣakọsilẹ gbogbo nnkan to yẹ kijọba mọ nipa ọrọ ọhun.

Nigba to n fesi, Fayẹmi dupẹ lọwọ igbimọ yii fun iṣẹ takuntakun, bẹẹ lo ni abọ iwadii naa yoo jẹ ki ijọba le fi owo ti wọn ṣawari yii ṣe awọn nnkan mi-in fun igbayegbadun awọn eeyan Ekiti.

O ni ko si aaye pe ẹnikan yoo jokoo si Eko, yoo si maa gbowo l’Ekiti mọ, bẹẹ ni ijọba ko ni i gba ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu laaye mọ.

Leave a Reply