Faith Adebọla, Eko
Ijọba ipinlẹ Eko ti kilọ pe kawọn eeyan to n gbe lawọn agbegbe bii Iwaya, Owode, Makoko, Badia, Ijọra, Pọta, Shibiri titi kan Agiliti, Agboyi, Itowolo ati Ajegunlẹ tete maa palẹ ẹru wọn mọ, ki wọn lọọ wa ibi ti wọn maa gbe lawọn agbegbe to bọ si oke odo, tori ojo ọdun yii maa pọ gan-an, o si ṣee ṣe ki omiyale yọ awọn eeyan agbegbe wọnyi lẹnu kọja aala. Wọn lọjọ bii ọgọrun-un meji, ọgọta o le ọkan ni ipinlẹ Eko maa fi gbalejo ejiwọwọ, o kere tan.
Kọmiṣanna fun ọrọ ayika ati omi, Ọgbẹni Tunji Bello, lo sọrọ yii l’Ọjọbọ, Tọsidee, fawọn oniroyin nigba to n kede abọ iwadii awọn onimọ nipa oju ọjọ ati iyipada asiko lori ipa ti ojo maa ni lori ipinlẹ Eko lọdun 2021.
Tunji ni akoko to ṣẹku ki ojo too balẹ yii ṣi pọ to fawọn to ba fẹẹ ko kuro nibi ti omiyale ti n ṣọṣẹ lati tete ṣe bẹẹ, tori ogun awitẹlẹ ki i pa arọ to ba gbọn.
O fi kun un pe ọpọ oṣu ni wọn ni awọn odo kaakiri ipinlẹ Eko maa fi kun akunfaya, tori ẹ, o ṣe pataki kawọn ti wọn n gbe leti odo atawọn ibi ti ọgbara nla maa n ṣan kọja ṣọra tabi ki wọn ṣi sa kuro nibẹ na.
Wọn ni ọjọ ti ojo maa fi rọ lọdun yii maa wa laarin okoolerugba o din meji (238) si ọtalerugba o le ẹyọ kan, o si le ju bẹẹ lọ.
Amọ ṣa o, kọmiṣanna naa ni ijọba ipinlẹ Eko ti n ṣiṣẹ pẹlu ajọ to n ri si ọrọ boju ọjọ ṣe ri ni Naijiria, iyẹn Nigeria Meterorological Agency (NiMET) lati la araalu lọyẹ, ati lati ṣeto bi awọn eeyan yoo ṣe gbe igbese ti ko ni i jẹ ki ẹmi ati dukia ṣofo sinu omiyale to rọ dẹdẹ ọhun.