Ijọba Eko ṣofin irinna tuntun ati ijiya nla fawọn to ba rufin

Faith Adebọla, Eko

Ijọba ipinlẹ Eko ti fihan pe wiwakọ lai bofin mu nipinlẹ Eko ki i ṣe ọrọ apara rara, latari bi gomina ipinlẹ naa, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu ṣe buwọ lu ofin irinna tuntun tawọn awakọ loju popo ni lati tẹle, pẹlu ijiya to gbopọn fun ọkọọkan awọn ofin naa. Wọn lofin ọhun ti bẹrẹ iṣẹ loju-ẹsẹ.

Ofin mẹrindinlọgbọn ni wọn to lẹsẹẹsẹ ninu iwe ofin irinna tuntun naa, gomina naa si sọ pe ki eku ile yaa gbọ, ko sọ fun t’oko ni, ki adan gbọ, ko lọọ ro f’oobẹ, tori ẹni ti wọn ba gba mu pe o ṣẹ sofin naa yoo sanwo itanran, tabi ki tọhun rẹwọn he.

Mẹfa lara ofin naa ni ko si sisanwo itanran tabi lilọ sẹwọn fun, arufin naa yoo padanu ọkọ rẹ sọwọ ijọba ni.

Eyi ni diẹ lara awọn ofin naa ati ijiya rẹ bi ijọba ipinlẹ Eko ṣe kede:

Ẹni to ba wakọ lai ni lansẹẹsi, tabi ti ọkọ rẹ ko niwee-ẹri pe ọkọ ọhun yẹ loju popo (Road Worthiness), tabi iwe hakin pamiiti (hackney permit), tabi to kọ lati lẹ ẹ mọ mọto rẹ, tabi to n fọkọ ṣe kabukabu lai gbaṣẹ ijọba, wọn yoo gbẹsẹ le ọkọ ọhun ni.

Ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira lowo itanran fun ọmọ ti ko ti i pe ọdun mejidinlogun lọjọ-ori to n wakọ, to ba si jẹ niṣe leeyan kọti ikun si oṣiṣẹ LASTMA tabi to ba wọn ṣagidi, iye owo kan naa lo maa san, tabi ki wọn gbẹsẹ le mọto rẹ, o si le jiya mejeeji.

Awọn mi-in lara ofin naa ni ijiya alapa meji tabi mẹta. Fun apẹẹrẹ, ẹni to ba n wa ọkọ ti wọn so ayederu nọmba mọ kiri yoo sanwo itanran ẹgbẹrun lọna ọgbọn tabi ko fẹwọn ọdun mẹta jura.

Ẹwọn oṣu mẹfa lẹni to ba n wakọ pẹlu iwe ọkọ tabi lansẹnsi ayederu yoo lọ.

Ẹgbẹrun lọna ọgọrin lowo itanran fun ẹni to kun ọkọ rẹ si kidaa ọda yẹlo (yellow) ti ko fi ọda dudu la a laarin, to si n fi mọto ọhun kero.

Oṣu mẹta ni wọn maa sọ ẹni to ba kọ lati duro nibi ti ina oju popo ba ti da a duro si, bẹẹ lẹni to ba n jẹun wakọ tabi to ba n fi ọwọ kan wakọ.

Ẹṣẹ nla ni ki dẹrẹba ọkọ maa mu siga wakọ, yoo san faini ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira tabi kijọba gba mọto lọwọ ẹ, oṣu mẹfa lẹwọn ẹni to ba lu oṣiṣẹ ijọba to n dari ọkọ loju popo fi n ṣere, yoo si tun san owo itanran ẹgbẹrun lọna aadọta naira.

Iwe ofin naa kun rẹrẹ fun oniruuru ẹṣẹ tawọn ọnimọto gbọdọ mọ nipa ẹ, titi kan wiwakọ lai ni ina, tabi wiwa mọto pẹlu ina oju kan, mọto ti taya rẹ ti la, wiwa ọkọ gba ọna ẹlomi-in, wiwa mọto lai de bẹliiti, ọkọ ti gilaasi iwaju tabi tẹyin ti fọ, diduro lori titi marosẹ tabi keeyan maa rifaasi ọkọ nibẹ.

Leave a Reply