Ijọba Eko fẹẹ ṣeto iranwọ fawọn ti wọn ba dukia wọn jẹ 

Aderounmu Kazeem

Igbakeji gomina ipinlẹ Eko, Ọbafẹmi Hamzat, ti ṣeleri fawọn eeyan ipinlẹ naa, paapaa awọn ti wọn padanu dukia wọn atawọn ti wọn ja sọọbu wọn wi pe ijọba yoo ṣeto iranwọ fun wọn.

Lana-an ọjọ Ẹti naa lo sọ ọ lori ayelujara abẹyẹfo ẹ, (Twitter), bẹẹ lo fi ikanni tawọn eeyan le lọ lori ẹrọ ayelujara ọhun lati forukọ silẹ ti wọn yoo fi lanfaani lati ri iranwọ gba lọwọ ijọba.

Ṣaaju asiko yii ni Gomina Babajide Sanwo-Olu ti kọkọ ṣeleri fawọn eeyan ipinlẹ Eko nigba to lọ kaakiri, to si ri bi wọn ti ṣe ba ọpọ dukia atawọn ileeṣẹ nlanla jẹ.

O sọ pe iṣẹlẹ to ba ni ninu jẹ pupọ ni, ati pe yoo gba ipinlẹ Eko ni ọpọ ọdun lati fi ṣatunṣe si gbogbo ohun ti wọn bajẹ yii.

Sanwo-Olu, sọ pe o ṣeni laanu wi pe ki i ṣe ipinlẹ Eko ti wọn gbe le oun lọwọ lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2019 niyi, nitori bi awọn ọbayejẹ kan ṣe sọ ipinlẹ Eko di nnkan mi-in bayii.

O ni, “Pẹlu bi a ti ṣe lọ kaakiri yii, ohun ti a n gbọ lẹnu awọn eeyan ni pe, alaafia lawọn n fẹ. Fun idi eyi, ijọba ko ni i fọwọ kekere mu ẹnikẹni to ba fẹẹ duro nipo adaluru tabi basejẹ, bẹẹ la rọ awọn eeyan to n gbe igbekugbe sori ayelujara lati dekun ẹ, ki wọn yee gbe ọkan awọn araalu soke lọna ti ko yẹ.”

 

One thought on “Ijọba Eko fẹẹ ṣeto iranwọ fawọn ti wọn ba dukia wọn jẹ 

Leave a Reply