Ijọba Eko ni ẹsun mẹrin lawọn maa ka si Baba Ijẹṣa lẹsẹ ni kootu

Faith Adebọla, Eko

Ijọba ipinlẹ Eko ti ni faili iwe ẹsun tawọn ọlọpaa lawọn ti fi ṣọwọ sọdọ ajọ to n gbeja araalu, to si n fun awọn adajọ nimọran, DPP (Directorate for Public Prosecution) lawọn n duro de, kawọn le wọ Ọlanrewaju James Omiyinka tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹṣa tuurutu re’le ẹjọ, wọn lẹsun mẹrin ọtọọtọ lawọn ti to jọ lati fi kan an ni kootu.

Ẹka to n ri si iwa ọdaran abẹle ati ifipananilopọ nipinlẹ Eko, DSVRT (Lagos State Domestic and Sexual Violence Team) lo sọrọ yii ninu atẹjade kan ti wọn fi lede lọjọ Ẹti, Furaidee, lori ọrọ gbajugbaja oṣere alawada to di afurasi ọdaran yii.

Akọkọ lara ẹsun ọhun ti wọn ni ẹwọn gbere nijiya ẹ ni pe afurasi ọdaran naa fipa ṣe kinni fọmọde, o si fi ‘kinni’ ba ọmọ labẹ jẹ. Wọn lẹsun yii ta ko isọri ọtalerugba ati ẹyọ kan (261) iwe ofin iwa ọdaran nipinlẹ Eko, tọdun 2015.

Ẹsun keji ni pe o gbiyanju lati fipa ba ọmọde sun, fẹẹ fipa ba a lo pọ, leyii to ta ko isọri ọtalerugba le meji (262) iwe ofin iwa ọdaran nipinlẹ Eko kan naa, ẹwọn ọdun mẹrinla lẹni to ba jẹbi maa fi jura.

Abẹ isọri ọtalerugba le mẹta (263) lẹsun kẹta bọ si, ṣoki lẹwọn eleyii, ọdun mẹta pere nijiya ẹ, to ba jẹbi fifi ibalopọ halẹ mọ ọmọde.

Ẹsun kẹrin ti wọn lawọn maa to siwaju adajọ ta ko Baba Ijẹṣa ni pe o fọwọ pa ọmọde lara lọna ti ko yẹ, eyi si le sin in lọ sẹwọn ọdun meje pere.

Atẹjade naa sọ pe awọn ti bẹrẹ si i ko ẹri jọ lati fi sọpọọti awọn ẹsun wọnyi nile-ẹjọ, wọn ni kedere lawọn wa lojufo si bi ọrọ Baba Ijẹṣa ṣe n lọ, awọn si n kiyesi igbesẹ iwadii tawọn ọlọpaa n ṣe lori ẹ, tori ijọba Eko ko fẹẹ gbooorun iwa palapala to jẹ mọ fifipa ba ọmọde ṣe katikati kankan, wọn lawọn o ni i daṣọ aṣiri bo ẹnikẹni tajere iru nnkan bẹẹ ba ṣi mọ lori, awọn maa fi tọhun jofin ni, lai ka bi iru ẹni bẹẹ ṣe le jẹ lawujọ si.

Leave a Reply